Nitori afikun owo-epo bẹntiroolu ati ina ijọba, awọn eeyan bẹrẹ ifẹhonu han l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan, iyẹn Coalition of Civil Societies, tipinlẹ Ọṣun, fọn sojuu titi laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii lati fẹhonu han lori afikun owo-epo bẹntiroolu ati owo ina tijọba kede rẹ laipẹ yii.

Lati aago meje aarọ ni wọn ti pejọ si Freedom Park, niluu Oṣogbo, pẹlu awọn agbofinro ti wọn duro wamuwamu.

Bii aago mẹjọ ṣe kọja ni wọn fọn si titi pẹlu oniruuru orin ati akọle lọwọ pe ki i ṣe ayipada ti Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC ṣeleri fawọn araalu niyi.

Ọkan lara awọn adari wọn, Comrade Waheed Saka, sọ pe awọn fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ marun-un pere lati tun ero rẹ pa lori igbesẹ naa, lai jẹ bẹẹ, awọn yoo bẹrẹ ifẹhonu han ti yoo mi gbogbo ipinlẹ Ọṣun titi.

Waheed ṣalaye pe pẹlu nnkan ti oju awọn araalu ri lasiko ajakalẹ arun Korona, ko yẹ kijọba tun gbe ẹru afikun owo epo bẹntiroolu ati owo ina le awọn araalu lori.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

One comment

  1. Oye ki awon ipinle to kun ni Naijiiria na darapo pelu won, ki ijoba apapo le mo pe kodun mo gbogbo ara ilu ninu rara

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: