Ọlawale Ajao, Ibadan
Niṣe lẹgbẹ awọn akẹkọọ nilẹ yii, iyẹn National Association of Nigerian Students (NANS) ẹkun D, ya si igboro ilu Ibadan lonii lati fẹhonu han lori afikun tijọba apapọ mu ba kun owo epo bẹtiroolu.
Oriṣiiriṣii patako pelebe pelebe ti wọn kọ oniruuru akọle si ni wọn gbe lọwọ lati ṣalaye fun gbogbo aye pe awọn ko fara mọ owo ti ijọba gbe gori iye ta a ti n ra epo bẹtiroolu nilẹ yii.
Awọn ipinlẹ ti ẹkun D ninu ẹgbẹ NANS ko sinu ni Ọyọ Ondo ati Ọṣun. Gbogbo ipinlẹ wọnyi la si gbọ pe awọn ẹgbẹ akẹkọọ nilẹ yii ti ṣeto iwọde alalaafia ọhun, paapaa lawọn olu ilu ipinlẹ naa bii Ibadan, Oṣogbo ati ilu Akurẹ.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun, Kazeem Israel ṣapejuwe eto ẹkunwo epo ati ẹkunwo to ṣẹṣẹ ba ina ilẹntiriiki naa gẹgẹ bii ọna lati fara ni araalu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Tabi ṣugbọn ko si nibẹ, ijọba to wa lori aleefa bayii ti da kun ipọnju ati inira ti ijọba ana (labẹ akoso Ọmọwe Goodluck Jonathan) da silẹ fawọn araalu.
“Eto ẹkọ ti di ohun ti awọn ijọba ko nawo le lori mọ lasiko yii. Wọn ko si naani ẹka eto ilera, paapaa lasiko ajakalẹ arun Korona yii, nigba to jẹ pe ilẹ okeere lawọn ijọba wa ti n lọọ gba itọju. Kinni ọhun tiẹ waa buru jai lasiko Aarẹ Buhari yii, o si ti jẹ ki awa akẹkọọ ri i gẹgẹ bii ohun to pọn dandan lati maa fẹhonu han si awọn aiṣedeede ijọba bayii gẹgẹ ba a ṣe maa n ṣe nigba kan.”
Agbẹnusọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa waa gba Aarẹ Buhari niyanju lati kọwe fipo silẹ bo ba mọ pe oun ko mọna lati ṣejọba ti yoo mu idẹrun ba gbogbo ọmọ orileede yii.