Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Akẹkọọ Fasiti imọ-ẹrọ tijọba apapọ to wa l’Akurẹ, Ọlọna Joseph Oluwapẹlumi, ni wọn lo ti binu pa ara rẹ lori idi ti ko tii ye ẹnikẹni.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, akẹkọọ ọhun, ẹni to ti wa ni ipele kẹta ni wọn ba nibi to pokunso si ninu yara ile to n gbe lagbegbe Aulẹ, niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Awọn akẹkọọ kan ti wọn jẹ ẹgbẹ oloogbe ọhun ni wọn ṣakiyesi pe ilẹkun yara rẹ ṣi wa ni titi pa lasiko ti wọn lọọ ki i laaarọ kutukutu ọjọ iṣẹlẹ naa.
Nigba ti wọn kan ilẹkun titi ti wọn ko ri ẹni da wọn lohun ni wọn pinnu lati ja ilẹkun yara rẹ, iyalẹnu lo si jẹ nigba ti wọn ba a nibi to ti n rọ diro diro lori iso pẹlu bọkẹẹti ipọnmi to fi ti ẹsẹ lasiko to n goke lati pokunso.
Awọn to sun mọ ọmọkunrin ti inagijẹ rẹ n jẹ Black ọhun daadaa ni lati bii ọsẹ diẹ sẹyin lo ti n fi ọrọ iku powe lori ikanni Fesibuuku rẹ.
Ọpọlọpọ igba ni wọn lo si maa n kọ ọ sibẹ pe oun n wa ẹni ti yoo fi owo ran oun lọwọ lori okoowo kan ti oun n ṣe.
Awọn ọrọ wọnyi lo jẹ kawọn eeyan kan maa ro pe ṣe ni akẹkọọ naa mọ-ọn mọ pa ara rẹ latari ironu aroju ati aisi oluranlọwọ fun un.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni oku akẹkọọ naa ti wa ni mọṣuari, ati pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lati fidi ohun to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.