Nitori idajọ ibo gomina, awọn ọmọ Oyetọla bẹrẹ aawẹ ati adura ọlọjọ meje l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn alakooso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati bẹrẹ aawẹ ati adura ọlọjọ meje lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to ṣẹ̀ṣẹ̀ pari yii lati fi wa ojurere Ọlọrun lori ẹjọ to wa ni kootu.

Lọsẹ to kọja ni igbẹjọ pari lori ẹjọ ti gomina ana, Alhaji Gboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC, pe ta ko ijawe olubori Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ẹgbẹ PDP ati ajọ INEC, ireti si wa pe igbimọ olugbẹjọ naa yoo gbe idajọ wọn kalẹ laipẹ.

Latari idi eyi ni Adele alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, ṣe sọ pe o pọn dandan ki ẹgbẹ naa ṣipẹ lọdọ Ọlọrun ni bayii ti wọn ti gbe oniruuru ẹri kalẹ ni kootu lati fi gba ẹtọ Oyetọla pada.

O ran gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa leti pe gbogbo nnkan lo nilo adura laye yii lati le ṣe aṣepe, ati lati le doju ija kọ awọn alagbara ibi okunkun aye yii.

Adele alaga yii sọ pe oun nigbagbọ pupọ ninu adura gbigba, o si rọ wọn lati ma ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aawẹ ati adura naa pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun ti oun n sin yoo ṣiṣẹ iyanu nla.

O ni ki wọn tẹ siwaju lati maa gbadura fun alaafia pipe fun Oyetọla ati igbakeji rẹ, Benedict Alabi, pẹlu idile wọn lasiko aawẹ ati adura naa.

Sooko Lawal sọ siwaju pe ki wọn ke pe Ọlọrun lati da ogo to ti bọ sọnu lọwọ ipinlẹ Ọṣun pada, ki ipinlẹ naa le goke agba bo ṣe wa tẹlẹ laarin awọn ẹgbẹ ẹ lorileede yii.

Leave a Reply