Ọlawale Ajao, Ibadan
Ajọ Yoruba Agbaye, iyẹn Yoruba World Centre, ti sun ifilọlẹ eto idije imọ Yoruba to fẹẹ fi lọlẹ laipẹ yii siwaju. Eyi ko ṣẹyin ipapoda Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Atanda Ọlayiwọla Adeyẹmi (Kẹta), ẹni to waja lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii.
Loṣu to n bọ, iyẹn inu oṣu Karun-un, ọdun 2022, ni wọn ti pinnu lati ṣe ifilọlẹ eto idije imọ Yoruba ọhun, eyi ti ajọ Yoruba World Centre gbe kalẹ fawọn akẹkọọ ileewe girama jake-jado ilẹ Yoruba titi de Kwara ati ipinlẹ Kogi, ṣugbọn inu oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn sun eto ọhun si bayii.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade ti adari igbimọ alakooso ajọ Ibudo Aṣa Agbaye, Ọgbẹni Alao Adedayọ, fi ṣọwọ sakọroyin wa, wọn ni nitori ipapoda Alaafin ni wọn ṣe sun eto ọhun siwaju lati fi bu ọla fun ọba nla naa nitori yatọ si pe Alafin jẹ ọba gbogbo ilẹ Yoruba, Ọba Adeyẹmi lo tun ṣe alaga ayẹyẹ nla ọhun lọjọ ti Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo, ṣi aṣọ loju ajọ Yoruba World Centre, n’Ibadan, fun gbogbo aye ri.
“A ko le yara kora wa jọ fun iru nnkan pataki bayii laarin oṣu kan pere ti ọba Adeyẹmi waja. Yatọ si pe baba jẹ ọba to ni akoleya ọrọ aṣa, iṣe ati itan Yoruba, kabiesi funra wọn ni wọn dabaa asiko ta a fẹẹ ṣe ifilọlẹ eto idije yii”. Bẹẹ l’Ọgbẹni Adedayọ sọ ninu atẹjade ọhun.
Nigba to n ṣedaro ipapoda ori ade naa, alaṣẹ ajọ Yoruba Agbaye yii, to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ iweeroyin ALAROYE, sọ pe “lọdọọ wa ni Yoruba World Centre nibi, iwaja Ọba Adeyẹmi dun wa yatọ, nitori lẹyin ta a ti fẹnu ko lori idasilẹ ajọ yii, Kabiesi lẹni akọkọ ta a kọkọ lọọ ba. Loju-ẹsẹ ni wọn tẹwọ gba a, wọn ṣeleri lati lo ohun gbogbo to wa ni ikapa wọn fun aṣeyọri eto naa.
“Latigba naa ni wọn ti sọ ara wọn di ọkan pataki ninu awọn opo to gbe ajọ yii ro, wọn ko si figba kankan yẹ lori akitiyan naa titi dọjọ ti wọn lọọ dara pọ mọ awọn baba nla wọn.
“Alaafin Adeyẹmi ki i ṣe ọba Ọyọ nikan, ọba gbogbo ọmọ Yoruba pata nibi gbogbo lorilẹ aye ni wọn jẹ. Ti wọn ba n sọ pe eeyan nimọ ijinlẹ nipa nnkan, kabiesi gan-an la ba maa pe ni orisun imọ aṣa ati iṣe Yoruba, nitori ko si nnkan naa ti baba yoo ṣe nigba aye wọn ti nnkan ọhun ko ni i ni aṣa Yoruba ninu.
“Ki i ṣe asọdun ọrọ rara ta a ba sọ pe aṣa Yoruba ni Kabiesi n mi sinu, oun ni wọn n sọ lẹnu, aṣa Yoruba ni wọn si fi lo gbogbo iṣẹmi wọn lorilẹ aye, lọjọ gbogbo aye wọn. Ani beeyan ba ri Alaafin Adeyẹmi, onitọhun ko ni lati wa nnkan kan lọ sibi kan nipa Yoruba mọ, odidi aṣa Yoruba loluwarẹ ti ri yẹn.
“Pẹlu ọgbẹ ọkan la fi ki gbogbo ọmọ Yoruba ku iṣẹyinde ọba wa. Paapaa ju lọ, a ki Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, atawọn ara ipinlẹ naa; a ki awọn ọba wa nilẹ Yoruba ati idile ori ade to rewalẹ aṣa yii. Tọrọ ẹnu lasan kọ, laarin ẹgbaagbeje ọdun sasiko yii, a o le ri iru ọba bii Alaafin Adeyẹmi, abi ta lo le jo bii baba? Ta lo le kọrin ewi bii wọn? Ta lẹni naa to mọ’tan, ti yoo si le maa sọ itan pẹlu ọjọ ati asiko ti iṣẹlẹ kọọkan waye lai ṣẹṣẹ maa yẹ iwe itan wo? Dajudaju, ko sẹni to le di awọn alafo ti Alaafin Adeyẹmi fi silẹ, afi ti yoo ba tun maa gbooro si i lo ku.”