Jide Alabi
Nitori arun korona to tun ti n ran bii ina alẹ kaakiri ilẹ wa, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti tun fofin de awọn ile-ijọsin nilẹ wa lori bi eto ijọsin yoo ṣe maa waye ni mọṣalaasi ati ṣọọṣi.
Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni gomina kede pe awọn ile ijọsin ko gbọdọ ṣẹ isin kọja wakati meji, ipejọpọ wọn ko si gbọdọ kọja aadọta eeyan lẹẹkan ṣoṣo ni mọsalaasi ati ṣọọṣi.
Yatọ si eyi, ijọba tun fofin de eyikeyii ipejọpọ, wọn ni ko gbọdọ si ayẹyẹ kanifa ati awọn ayẹyẹ oriṣiiriṣii ti wọn maa n ṣe lasiko ọdun.
Siwaju si i, gomina ni ofin to de awọn ile-ijo ṣi wa sibẹ, ko gbọdọ si ile-ijo kankan to gbọdọ patẹ titi ti aṣẹ mi-in yoo fi jade.
Gomina gba awọn ileeṣẹ, awọn olokoowo ati awọn aaye kaakiri ki wọn ṣi tesiwaju pẹlu ofin ‘Ko si ibomu, ko si iwọle’ iyẹn ni pe ẹni ti ko ba ti bo imu rẹ ko gbọdọ ni anfaani si awọn ileetaja, awọn ibi iṣẹ ati ibi ti awọn ero pọ si.
Bakan naa nijọba ti tun paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn wa lati ipele mẹrinla sisalẹ lati maa ṣiṣẹ wọn nile lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, di ọjọ kẹrinla si asiko naa.
Bẹẹ nijọba ni ofin konilegbele to bẹrẹ lati aago mẹrin aarọ tijọba apapọ ṣe ṣi fidi mulẹ. Sanwoolu waa dupẹ lọwọ awọn ara Eko fun aduroti wọn, bẹẹ lo ni ara oun ti n ya.