Nitori awọn ajinigbe, ọkada gigun deewọ ni ipinlẹ Niger

Faith Adebọla

ọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, o ni ẹnikẹni to ba gun ọkada, boya aladaani tabi niṣe lo fi n gbe ero, ijọba maa mu un bi janduku arufin ni, awọn si maa foju ẹ ri mabo.

O lawọn to n fi ọkada ṣiṣẹ akanṣe paapaa ko gbọdọ gun alupupu wọn kọja aago mẹfa irọlẹ, tabi ṣaaju aago mẹsan-an owurọ.

Igbakeji gomina naa ni ijọba ti fọrọ yii to gbogbo awọn ọba, ẹmia, ẹgbẹ ọlọkada, awọn ijoye, atawọn alaga ijọba ibilẹ leti, ki kaluku le kilọ fawọn eeyan wọn, ki eku ile gbọ ko sọ fun toko.

O ni iṣoro aabo tawọn n koju ẹ yii ti de gongo, awọn si ti kiyesi i pe ọkada gigun wa lara ohun to mu ki eto aabo mẹhẹ, tori lọpọ igba, ọkada lawọn agbebọn maa n gun lati waa ṣe araalu ni ṣuta.

Leave a Reply