Dada Ajikanje
Bi Sunday Igboho, ṣe bọ sita to sọ pe oun ko fẹẹ ri awọn Fulani darandaran nipinlẹ Ọyọ mọ, paapaa lagbegbe Oke-Ogun ti wọn ti n paayan, ti wọn tun n ji eeyan gbe, Gomina Ṣeyi Makinde ti sọ pe oun ko fẹẹ gb̀ọ iru aṣẹ bẹẹ latọdọ ẹnikẹni.
Lori tẹlifiṣan ipinlẹ Ọyọ ni Ṣeyi Makinde ti sọrọ yii lasiko to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.
O ni bo ṣe wa ninu ofin orilẹ-ede yii, oun gẹgẹ bii gomina ṣetan lati maa daabo bo gbogbo awọn eeyan ti wọn n gbe nipinlẹ Ọyọ, ati pe gbogbo ọmọ Naijiria ni wọn lẹtọọ lati gbe ibikibi to ba wu wọn.
Gomina yii ti waa kilọ pe ẹnikẹni, yala ẹgbẹ tabi awọn eeyan kan ko gb̀ọdọ fi ipa le ẹnikẹni kurọ nipinlẹ ̀ọhun. Bẹẹ lo sọ pe ti ẹnikẹni ba ta ko ofin yii, ọwọ ofin loun yoo fi jẹ iru ẹni bẹẹ niya.
O ni ijọba oun ti gbọ bi awọn eeyan kan ṣe n halẹ kiri pe ki awọn Fulani kuro l’Ọyọọ, bẹẹ loun lodi is iru igbesẹ bẹẹ.
O ni wahala gidi niru awọn eeyan bẹẹ n wa fun ara wọn pẹlu igbesẹ wọn yii ti wọn ko ba jawọ.
O lawọn ọta ipinlẹ naa ki i ṣe Hausa tabi awọn Fulani to jẹ pe ohun ti wọn yoo fun awọn maaluu wọn jẹ ni wọn n wa kiri, ti maaluu ọhun yoo si pada di ọja ti wọn yoo ta fun araalu lati gba owo sapo ara wọn.
O ni ọta kan ti ipinlẹ ọhun ni bayii ni awọn janduku agbebọnrin, awọn to n ji eeyan gbe atawọn adaluru mi-in ti wọn ko ni iṣẹ meji ju bi wọn ṣe n fooro ẹmi awọn eeyan lọ.
O ti waa pe fun ifọwọsowọpọ araalu atawọn ọba alaye pẹlu awọn ẹṣọ agbofinro ki alaafia ati eto aabo to peye le wa daadaa nipinlẹ naa.
Pẹlu ọrọ ti Gomina Makinde sọ yii, o ti fi han pe awọn mejeeji ti jọ fẹẹ kẹsẹ bọ ṣokoto kan naa.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ti Sunday Igboho fun awọn Fulani ilu Igangan da lati ko ẹru wọn kuro niluu naa ni awọn eeyan n duro de. Wọn n reti boya ọkunrin naa yoo lọ siluu Igangan gẹgẹ bo ṣe ṣeleri abi ko ni i lọ.