Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari itu tawọn ajinigbe n pa lọwọ lawọn apa ibi kan nipinlẹ Ondo, ẹṣọ Amọtẹkun ti bẹrẹ ṣiṣe ayẹwo si awọn ọkọ to n rin lawọn oju popo.
Oludariwọn nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ lo sọrọ yii lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ nileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ.
Adelẹyẹ ni awọn ko ṣe agbekalẹ eto ọhun lati dẹruba ẹnikẹ́ni bi ko ṣe ki eto aabo le duro daadaa, ki awọn araalu si le lanfaani lati ṣe ọdun to n bọ yii pẹlu alaafia.
O rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya, ki wọn si maa gbiyanju lati mu awọn ohun eelo idanimọ wọn lọwọ nigbakugba ti wọn ba n jade.
Adelẹyẹ bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ kikun lati ọdọ awọn awakọ, ki wọn ma si ṣe ri i bii ifiyajẹni tabi fifoju ẹni rare nigba tawọn ẹsọ Amọtẹkun ba da wọn duro lati yẹ ọkọ wọn wo.
Gbogbo awọn to n lo ọkọ onigillasi dudu lo kilọ fun lati ri i daju pe wọn gba iwe to ba yẹ lati ọdọ awọn agbofinro, bakan naa lo ran awọn eeyan leti pe ofin to de iṣọwọ ṣiṣẹ awọn ọlọkada si wa digbi.
Awakọ tabi ọlọkada to ba ti ṣẹ si eyikeyii ninu awọn ofin ti wọn fi de wọn nipinlẹ Ondo lo ni awọn yóò ba ṣẹjọ lẹyin ti jọba ba ti gbẹsẹ le ọkọ tabi ọkada iru arufin bẹẹ.
Oloye Adelẹyẹ ni eeyan meje lọwọ awọn ti tẹ laarin ọjọ kín-in-ni, oṣu kejila, ọdun ta a wa yii, ti eto naa bẹrẹ.