Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti kilọ fawọn eeyan to wa lawọn ipinlẹ to wa lẹkun Guusu Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii lori bawọn ajoji ṣe n fi ojoojumọ ya wọle lati apa Oke-Ọya.
Adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo ṣe ikilọ yii lasiko to n ṣafihan awọn mejidinlaaadọsan-an mi-in tọwọ tun tẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lẹyin bii ọjọ mẹrin ti wọn ti kọkọ ṣawari awọn eeyan bii mọkanlelaaadọjọ ninu ọkọ ajagbe mẹta to n ko wọn bọ lati Oke-Ọya.
Ninu alaye to ṣe fawọn oniroyin, Oludamọran fun gomina lori eto aabo ni maaluu nikan la kọkọ ro pe ọkọ ajagbe naa ko ka too da a duro ni ibamu pẹlu eto duro-ka-yẹ-ọ-wo (stop and search) to n lọ lọwọ.
‘Ohun ta a ba ninu ọkọ ajagbe ọhun jọ wa loju pupọ nigba ta a da a duro tan. Awọn maaluu ni wọn ko soke patapata lori pako gbọọrọ gbọọrọ ti wọn tẹ soke ọkọ naa, wọn to ọkada bii ogoji sabẹ awọn pako ti wọn ko maaluu si, ki wọn too sin awọn eeyan to le lọgọrun-un kan sabẹ awọn ọkada naa nisalẹ patapata.
‘Ọna ti wọn gba sin awọn eeyan ọhun mọ ara wọn ya ni lẹnu pupọ, ṣe ni wọn to wọn lori ara wọn, b’eeyan o ba si wọnu ọkọ naa paapaa, ko ni i mọ pe iye awọn to to bẹẹ lo ko.
‘Ka ma tan ara wa jẹ, mi o ro pe eeyan kan to lẹjẹ lara le gba ki wọn sin oun bẹẹ mọ inu ọkọ pẹlu irora nla lai ni iṣẹ ibi kan pato to fẹẹ lọọ ṣe nibi to n lọ, kayeefi nla lo si n jẹ fun emi gan-an ọna ti awakọ ọhun fi raaye sin eeyan bii mejidinlaaadọsan-an mọ aaye kekere to ku ninu ọkọ rẹ.
‘Nigba ta a si n fọrọ wa wọn lẹnu wo, ohun kan ṣoṣo ti wọn n tẹnu mọ ni pe, ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, lawọn n bọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri ẹnikẹni tọka si pe oun lo ranṣẹ si awọn tabi ki wọn mọ ẹni ti wọn fẹẹ lọọ ba ati ibi ti wọn n lọ, leyii to fidi rẹ mulẹ pe bi wọn ṣe n fi ojoojumọ ya wọ ipinlẹ Ondo mu ifura nla lọwọ.
‘Loootọ la ṣi n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ, ṣugbọn mo ni lati kilọ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo ki olukuluku maa kiyesara, nitori pe oju ni alakan fi n ṣọri, ṣebi awọn tọwọ tẹ wọnyi nikan la ri, ta a lo mọ aimọye awọn ti wọn ti gbọna ẹburu wọle saarin ilu lai mọ. Ọpọlọpọ oogun buruku la ba lọwọ awọn ta a mu, bẹẹ ni wọn ko tun ri iwe to nilaari kan fi silẹ lori awọn ọkada ta a ba nikaawọ wọn.
‘Iwadii ti n lọ lọwọ lori awọn ọkada naa, ẹnikẹni ti iwadii ba fidi rẹ mulẹ pe ṣe lo ji eyikeyii ninu awọn ọkada ọhun la maa wọ lọ sile-ẹjọ. Bakan naa la ṣetan lati da gbogbo awọn ti ko ba ti ni ohun pato kan ti wọn fẹẹ waa ṣe pada si ipinlẹ koowa wọn.
‘Ko si idi meji ta a fi n gbe awọn igbesẹ ta a n gbe naa ju ọrọ eto aabo to mẹhẹ lọ, a n gbiyanju ki awọn oniṣẹẹbi ma baa lo awọn to n gbọna ẹburu wọle ọhun lati da omi alaafia ipinlẹ wa ru, a si ti pinnu pe a ko ni i gba ẹnikẹni ti ko ba ti ni ami idanimọ to daju tabi ti ko niṣẹ ati okoowo kan pato to fẹẹ ṣe laaye lati maa rin bo ṣe wu u lawọn oju ọna to gba agbegbe Guusu Iwọ-Oorun kọja.
‘Ẹyin naa ẹ jẹ ka ronu si i, ki lo le ṣokunfa bawọn eeyan kan ṣe n ha ara wọn mọ aarin apo irẹsi, ẹwa ati aarin awọn ẹranko lori pe wọn fẹẹ rin irinajo lọ sibi kan, ọpọlọpọ awọn ẹṣọ alaabo ni wọn ti fi eyi tan jẹ loju ọna nitori ko sẹni to le tete fura pe awọn eeyan kan wa labẹ ẹru ti ọpọ awọn awakọ lati Oke-Ọya naa n ko wọle.
‘Awọn ta a kọkọ ri ko lọjọ diẹ sẹyin la ti da pada si ipinlẹ wọn lẹyin ta a ti fọrọ wa wọn lẹnu wo, ta a si ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ko niṣẹ kan ti wọn ni lọkan lati waa ṣe nipinlẹ Ondo.
‘A ti ranṣẹ pe ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ Miyẹtti Allah nipinlẹ Ondo, lati waa wo o boya a ri ẹni to da mọ ninu gbogbo awọn ta a ti ko, ohun to si sọ fun wa lẹyin to wo wọn tan ni pe ko si eyi toun mọ ninu wọn, bẹẹ ni awọn naa ko si mọ oun, o ni ko sẹni to ba oun sọ ohunkohun lori irinajo awọn afurasi ọhun. Ohun ta a fidi rẹ mulẹ ninu iwadii ta a ṣe ni pe, ọpọ awọn arinrin-ajo naa ni wọn wa lati ipinlẹ Jigawa ati Kano, wọn ko nibi kan pato ti wọn n lọ, ibi ti wọn ba duro si lẹbaa ọna lawọn awakọ naa ti n gbe wọn lọkọọkan, ejeeji sinu ọkọ, ti wọn si n ko wọn wa silẹ Yoruba, ohun ti wọn maa n sọ fun wọn ni pe ki wọn ṣaa wọnu ọkọ na, o digba ti wọn ba de bi ti wọn n ko wọn lọ ki awọn too ṣalaye iṣẹ ti wọn fẹẹ lọọ ṣe fun wọn.
‘Ko si ani-ani p’awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ labẹ ofin lati lọ sibikibi to ba wu wọn lorilẹ-ede wọn, ṣugbọn ọna to ta ko ofin tawọn eeyan naa n tọ la o ni i faaye gba rara’.