Wọn ti mu marun-un ninu awọn apaayan to kọ lu ṣọọṣi Katoliiki Ọwọ lọjọsi

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afẹmiṣofo ti wọn ṣakọlu si ṣọọṣi Katoliiki Saint Francis, to wa niluu Ọwọ, ipinlẹ Ondo, laipẹ yii.

Ọga agba fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun Lucky Irabor, lo ṣe ikede yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lolu-ileeṣẹ ologun to wa l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ yii.

Ọgagun naa ni awọn ṣọja, atawọn ẹṣọ alaabo ti ki i ṣe ṣọja ni wọn jọ fọwọsowọpọ ṣiṣẹ naa.

Iraboh ko sọ iye afurasi apaayan ti wọn mu, bẹẹ ni ko sọ ọjọ ati ibi ti wọn ti mu wọn, ṣugbọn o sọ pe iṣẹ iwadii ṣi n lọ labẹnu, awọn yoo si tubọ jẹ karaalu mọ bi nnkan ṣe n lọ si, to ba tasiko.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ọjọ Aiku, Sannde, ni iṣẹlẹ agbọ-bomi-loju naa waye, nigba tawọn afẹmiṣofo kan dibọn bii olujọsin, tawọn ẹlẹgbẹ wọn yooku si ya bo ileejọsin Katoliiki ọhun bo ṣe ku diẹ ki wọn pari isin ọjọ isinmi naa, wọn pa ọpọ eeyan, wọn si ṣe ọgọọrọ leṣe, ki wọn too sa lọ.

Latigba naa ni awọn agbofinro ti wa lẹnu iṣẹ lati wa awọn olubi apaayan naa lawari.

Amọ, Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ti fidi ọrọ yii mulẹ. O sọ lọjọ Tusidee yii pe, “Mo kin ọrọ ti olori ologun sọ lẹyin, loootọ ni, ọsẹ to kọja lọwọ tẹ marun-un ninu awọn to ṣakọlu naa, wọn fi fọto wọn ranṣẹ si mi. Wọn ṣi n wa awọn yooku, wọn lati mu wọn.”

CAPTION

Leave a Reply