Eeyan mẹta ku, ọpọ fara pa, nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọrọ di bo o lọ o yago lọna, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fija pẹẹta lagbegbe Olunlade, Michael Imodu, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi ti eeyan mẹta ti ku, ti ọpọ si fara pa yannayanna.

Ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn ni wahala yii bẹrẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kunkun ti wọn n jija agba lagbegbe Olunlade si Michael Imodu, ti wọn n rẹ ara wọn danu bii ila, ti wọn si n rọjo ibọn. Gbogbo awọn to n taja lagbegbe naa fi ọja wọn silẹ wọn sa lọ, gbogbo awọn awakọ igboro, to fi mọ awọn ọlọkada, ni wọn n lọri pada, ti gbogbo opopona si da paro-paro, gbogbo awọn to sa wọle ni wọn ti ilẹkun mọri.

Lẹyin ti gbogbo ija naa rọlẹ tan ni wọn ri oku eeyan mẹta lojupopo, ti ko si sẹni to le wo oju wọn debi ti wọn aa mọ awọn to ku ọhun.

Leave a Reply