Nitori bi awọn tọọgi ṣe lu wọn lalubami, awọn nọọsi fẹhonu han l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

 

Ẹgbẹ awọn nọọsi ileewosan ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ, ni wọn jade laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati fẹhonu han ta ko bawọn kan ṣe ya wọnu ọgba ọsibitu ọhun, ti wọn si lu wọn lalubami.

Awọn nọọsi ọhun ni wọn kọ lati ṣiṣẹ bẹẹ ni wọn pinnu pe awọn ko ni i pada sẹnu iṣẹ titi tijọba yoo fi ṣeto aabo to peye fawọn ninu ọgba ileewosan naa.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, ni wọn lawọn eeyan kan binu lu gbogbo awọn nọọsi to wa lẹnu iṣẹ lẹyin ti alaisan tí wọn gbe wa fun itọju deedee ku lairotẹlẹ.

Awọn ẹbi oloogbe naa la gbọ pe wọn fẹsun kan awọn nọọsi to wa lẹnu iṣẹ lọjọ naa pe aitete kọbiara si itọju eeyan wọn lo ṣokunfa iku rẹ.

Ọpọ awọn ti wọn lu ọhun la gbọ pe wọn ṣi n gba itọju lọwọ nileewosan yii kan naa.

Dokita Liasu Ahmed to jẹ ọga agba ileewosan ijọba apapọ ilu Ọwọ to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni ẹkunrẹrẹ iwadii ti bẹrẹ lori rẹ.

O fi awọn osisẹ abẹ rẹ lọkan balẹ pe eto ti n lọ lọwọ lati peṣe aabo fun wọn.

Leave a Reply