Monisọla Saka
Ọkan lara awọn oṣerekunrin ilẹ wa, Alesh Sanni, ti bu ẹnu atẹ lu iwa awọn eeyan wọn nidii iṣẹ tiata, nitori iha ti wọn kọ si gbajumọ ọkunrin alafẹ to maa n ṣe bii obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, lẹyin tọkunrin naa dero atimọle.
Alesh binu sọrọ sawọn ẹgbẹ rẹ, o ni alabosi ati ajẹnifẹni ni wọn. Ọmọkunrin naa ni nitori anfaani ti wọn n ri lara ọkunrin to maa n pe ara ẹ lobinrin, to si maa n ṣe bii obinrin yii ni gbogbo ifẹ ti wọn fi n han si i ko too dero ọgba ẹwọn.
Alesh sọ pe ọgba ẹwọn ki i ṣe ibi to yẹ ọmọ eeyan, o waa bu ẹnu atẹ lu awọn oṣere yii pe ko sẹni to ya si Bobrisky mọ latigba to ti wọ ẹwọn.
“Ọgba ẹwọn ki i ṣe ibi teeyan gbọdọ duro si fun ọjọ kan pere. Mi o mọ idi tawọn eeyan fi labosi bẹẹ, ohun tẹ ẹ fi n ye mi bayii ni pe a le pe Bobrisky fun ode ariya, lati ṣe igbelarugẹ fawọn fiimu wa, orin ati lati ba wa mu ode ayẹyẹ wa dun, titi kan oko-owo wa pẹlu ẹrọ ayelujara rẹ, nitori iru igbesi-aye to n gbe, eyi tawa o ri bii babara tabi nnkan ti ko daa.
“Ni bayii, nitori ohun yoowu to le jẹ, wọn ti fi panpẹ ọba mu un, wọn si ti sọ ọ sẹwọn, sibẹ, gbogbo wa dibọn bii pe ko ba wa ṣe ri ni. Ki lo de tawọn eeyan ya ika to bayii? Agaga awa ilu-mọ-ọn-ka. Ẹ ranti pe ohun to wa nilẹ yii le ṣẹlẹ si ẹnikẹni o.
Mo wa pẹlu rẹ ninu adura, Idris Okunẹyẹ. Mo n gbadua fun ẹ, Idris Okunẹyẹ, Ọlọrun aa ko ẹ yọ”.
Bayii ni ọkunrin onitiata yii ṣe sọ.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni adajọ sọ Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa, latari ẹsun ṣiṣe arọndarọnda owo ati titabuku owo Naira ti ajọ EFCC fi kan an.
Ọna ti Bobrisky gba nawo, eyi ti wọn ni ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu ni, ni wọn lo ta ko o ni kootu. Eyi to waye kẹyin, to si ṣakoba fọkunrin yii, ni owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo Naira, to na nibi ayẹyẹ afihan fiimu tuntun ti Ẹniọla Ajao ṣe loṣu Kẹta, ọdun yii.
Eyi lo ṣokunfa ọrọ ti Alesh sọ, tawọn eeyan ori ayelujara naa si gbe e lẹyin pe ẹni t’aye ba n ri lo ni wọn mọ. Wọn ni oju aye ni wọn ri yẹn. Ati pe ti ori ba ko Bobrisky yọ, to ba jade lẹwọn, afi ko bẹrẹ igbe aye ọtun to dara, ko si mọ awọn eeyan to le maa ba ṣe pọ, nitori awọn eeyan to ṣokunfa bo ṣe debẹ naa ni ko ya si i mọ yẹn.