Kazeem Aderohunmu
Peter Ayọdele Fayoṣe sọ lasiko ti ẹgbẹ naa n n ṣe ifilọlẹ eto idibo sileegbimọ aṣofin pe, niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ PDP Eko fẹyin baba ọhun ti bayii ninu ẹgbẹ.
Fayoṣe sọ pe ti ẹgbẹ naa ba fẹẹ laṣeyọri gidi nipinlẹ Eko, afi ki wọn yọwọ Bọde George kuro ninu ọrọ ẹgbẹ oṣelu naa.
Ọrọ to da wahala silẹ ree, bẹẹ lẹni to jẹ Alukoro fun ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gani Taofeek, ti sọ pe ọrọ ti Fayoṣe sọ yii le da ẹgbẹ ru, ati pe o le mu awọn ọdọ kọju oro si Oloye Bọde George, ti nnkan si le ṣe bẹẹ daru mọ ẹgbẹ naa lọwọ nipinlẹ naa.
Wọn ti sọ pe Fayoṣe gbọdọ tọrọ aforiji ni, ti ko ba fẹẹ ki ẹgbẹ da sẹria nla fun oun lori ọrọ yii.
O fi kun un pe ki i ṣe iru asiko ti PDP n palemọ gidigidi lati gba ipinlẹ Eko mọ APC lọwọ, paapaa fun ipo gomina lọdun 2023, lo yẹ ki Fayoṣe sọ ọrọ to le tu ẹgbẹ ọhun ka.
Ni bayii, wọn ti fun un ni ọjọ meje ko fi ṣatunṣe si ohun to ṣe yii, bakan naa ni wọn fi kun un pe ti ko ba tọrọ aforiji, ko ni i lẹtọọ lati kopa ninu eto kankan ti ẹgbẹ ba n ṣe, nitori ọkunrin naa ko duro gẹgẹ bii awokọṣe rere fawọn ọdọ ninu ẹgbẹ naa.