Ọlọkada atero ku lọjọ Aiku, tirela lo tẹ wọn pa ni Mowe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iku oro gbaa lo pa ọkunrin ọlọkada kan atero to gbe sẹyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa yii, bẹẹ oun lo fi oju ọna tiẹ silẹ to n gba apa ibi ti ki i ṣe tirẹ rara ni Mowe, ipinlẹ Ogun, nigba  naa lo pade tirela, iyẹn si run un pa pẹlu ero to gbe sẹyin, lawọn mejeeji ba dero ọrun ojiji.

Aago mẹwaa aarọ nijamba yii waye gẹgẹ bi Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, se ṣalaye lọsan-an ọjọ naa.

O ni PKA 147 VF ni nọmba tirela ti ọkada naa bọ si lẹnu yii, ati pe lati Redeemed ni ọlọkada naa ti n tọ oju ọna ti ki i ṣe tiẹ bọ, ko too waa pari ẹ si Mowe.

Pẹki lo ko tirela to n lọ si Interchange ni tiẹ lai si ọna abayọ, nigba ti ọlọkada atero to gbe naa yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, tirela ti tẹ wọn pa.

Ko si kinni kan ti ẹnikan le ṣe si i mọ, niṣe ni wọn ko awọn mejeeji to doloogbe naa lọ si ile igbokuu-si Fakọya, ni Ṣagamu, wọn si gbe tirela ati ọkada lọ si teṣan ọlọpaa.

Ajọ TRACE rọ awọn awakọ ati ọlọkada to n fi oju ọna wọn silẹ gba ti ẹlomi-in pe ki wọn yee ṣe bẹẹ, paapaa loju ọna marosẹ, nitori ewu to wa nibẹ ki i kere, o maa n la iku lọ ni.

 

Leave a Reply