Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, koda, eeyan a maa ke nigba mi-in ti idunnu ba ṣubu lu ayọ fun un. Iru ẹ lo ṣẹlẹ si Alaaja Risikat Ejide Adebayọ, iyawo Ọga Bello onitiata ati iya to bi Fẹmi Adebayọ toun naa jẹ oṣere. Niṣe ni mama n sunkun ayọ l’Ọjọbọ to kọja, nigba to pe aadọrin ọdun, tawọn ọmọ rẹ si fi mọto ayọkẹlẹ tuntun ta a lọrẹ.
Yatọ si Alagba Adebayọ Salami to jẹ ọkọ iya yii to wa nibẹ lọjọ naa, awọn ọmọ rẹ atawọn alabaṣẹ gbogbo lo tun yi i ka, bẹẹ ni apẹṣa kan bẹrẹ si i ki Alaaja Ejide ni mẹsan-mẹwaa, to n wure fun un pẹlu alaye pe awọn ọmọ rẹ lo ni koun ki i o.
Nigba ti wọn gbe mọto ayọkẹlẹ funfun naa jade, inu Iya Fẹmi dun, ṣe o ti n jo tẹlẹ, bẹẹ lo n nawo tawọn to wa nibẹ naa tun n nawo fun un. Ṣugbọn nigba ti mama naa ri mọto, inu rẹ dun, awọn ọmọ n di mọ ọn, oun naa n di mọ wọn pada, ori iya naa wu, omije ayọ si bẹrẹ si i jade loju rẹ.
Ṣaaju ni Fẹmi Adebayọ ti kọkọ kọ ọrọ iwuri soju opo Instagraamu rẹ lọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ti mama rẹ pe aadọrin ọdun ( 70 years).
Eyi lohun ti ọkunrin tawọn eeyan mọ si Jẹlili oniso naa kọ “Oni lọjọọbi iya mi pataki!!!. Ẹ jọọ, gbogbo aye, ẹ ba mi ki wọn ku ọjọọbi aadọrin ọdun. Hmmmm… EJIDE! Oriṣa bii iya o si… Abiyamọ bọja gbọọrọ-gbọọrọ…Ọpọlọpọ nnkan ni iya mi jẹ, ṣugbọn eyi to bori gbogbo ẹ ni Ifẹ. Oun gan-an nitumọ ifẹ tootọ.
“Ti mi o ba jẹun… iya mi o ni i jẹun.. Adura ti mo n gba lojoojumọ ni pe ti mo ba tun fẹẹ tunle aye wa nigba miliọnu mẹwaa, k’Ọlọrun jẹ ki n tun gba ọdọ rẹ wa. Mọmi, mo fẹran yin pupọ, lagbara Ọlọrun, mo maa ṣayẹyẹ ọgọfa ọdun yin laye ninu alaafia ara ati ọpọlọpọ ibukun. Ejide.. Gbogbo wa la nifẹẹ yin, ẹ maa dagba lọ ninu alaafia ara ati ifọkanbalẹ.”