Nitori ẹgbẹrun kan Naira, wọn gun akẹkọọ Fasiti Akungba Akoko pa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn akẹkọọ Faṣiti Adekunle Ajasin, to wa niluu Akungba Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun, Temitayọ Ayọdeji, la gbọ pe wọn gun lọbẹ pa ni irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Ọmọkunrin ọhun tawọn eeyan mọ si Daddy Yo la gbọ pe ọmọ oniluu kan ti a ko ti i morukọ rẹ gun pa latari ede aiyede to waye laarin wọn nitori ẹgbẹrun kan Naira.

Ohun ta a gbọ ni pe ile iya afurasi ọdaran ọhun to wa lagbegbe kan ti wọn n pe ni Okusa, niluu Akungba Akoko, ni iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ yii ti waye. Wọn ni iya rẹ lo ni ile ọhun.

Wọn ni orin ti ọmọkunrin ọhun fi bọnu lẹyin to gun Daddy Yo lọbẹ tan ni pe ọrọ naa ti di wan – sẹro (1-0) leyii to mu kawọn eeyan maa ro pe o ṣee ṣe ki iku akẹkọọ ọhun wa lati ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Daddy Yo to wa niplele kẹrin, lo ṣẹṣẹ pari idanwo aṣekagba rẹ laipẹ yii, to si jẹ pe purojẹẹti to fẹẹ difẹndi lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ta a wa yii lo ku to n da a duro sileewe ọhun ti ko fi ti i pada sọdọ awọn obi rẹ.

Ọkunrin to ṣiṣẹ ibi naa la gbọ po ti sa lọ ni kete to pa ọmọkunrin naa tan. Eyi lo ṣokunfa bi awọn ọdọ kan ṣe fọn si igboro lati fẹhonu han ta ko iṣẹlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe awọn ọdọ tinu n bi ọhun ti dana sun ile meji, ile iya ọdaran yii, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye gan-an ni wọn kọkọ dana sun, ki wọn tun too sun ile miiran.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lasiko ta a kan si i lori aago, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni oun ko ti i le sọ ohun to ṣokunfa iku gbigbona ti wọn fi pa ọmọkunrin naa lasiko to n ba wa sọrọ. O ni awọn ọlọpaa ti wa ni gbogbo agbegbe naa, ki alaafia le jọba.

Leave a Reply