Nitori ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, Inuwa sọ ọrẹ rẹ loko pa

Adewale Adeoye

Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, ṣe lọrọ Ọgbẹni Yunan Inuwa, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), kan ṣi n ya awọn to gbọ lẹnu pẹlu bo ṣe lẹ ọrẹ rẹ, Augustine Otti, loko pa, to si tun ji ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un  Naira to wa lapo rẹ gbe sa lọ, ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ laipẹ yii, to si ti n ka boro-boro lori ohun to mọ nipa iku oloogbe naa fun wọn.

ALAROYE gbọ pe ọrẹ imulẹ lawọn mejeeji yii, ti wọn si jọ n gbe lagbegbe Gyawana, nijọba ibilẹ Lamurede, nipinlẹ Adamawa, ko too di pe eṣu ya Yunan yii lo, to si pa ọrẹ rẹ danu nitori owo nla kan to ri lapo rẹ.

Gẹgẹ bi alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Adamawa, S.P Suleiman Nguroje, ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n foju Inuwa han ṣe sọ, o ni ni nnkan bii ago mẹjọ aṣaalẹ, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, ni oloogbe naa sọ fun ọrẹ rẹ pe ko tẹle oun lati lọọ sanwo apo irẹsi toun ra lawin lọdọ onibaara oun kan to wa lagbegbe Mbemum.

Gbara ti ọdaran naa ri i pe owo nla lo wa lọwọ oloogbe naa lowo ọhun ti wọ ọ loju, to si ti pinnu lati ṣe ọrẹ rẹ yii ni ṣuta, ko le ri owo to wa lọwọ rẹ gba.

Ọmọkunrin yii mu ipinnu rẹ ṣẹ pẹlu bo ṣe la ori oloogbe naa mọ okuta nla kan bayii lakooko ti wọn n ṣere lọwọ. Nibi ti oloogbe naa ti n ja raparapa lọwọ lo ba tun ti i sinu gọta nla kan. Inu gọta naa lo ti bẹrẹ si i lẹ ẹ lokuta titi ti Augustine fi ku patapata, to si ji owo to wa ninu apo rẹ gbe sa lọ.

Alukoro ọhun ni lara ohun to jẹ ki ọwọ tete tẹ Inuwa ni pe awọn ri awọn ohun kọọkan to jẹ ti ọdaran naa nibi to pa ọrẹ rẹ si, tawọn si ṣiṣẹ le e lori titi ọwọ fi tẹ ẹ.

O ni gbara ti ọwọ tẹ ẹ, lo ti jẹwọ pe loootọ, oun loun pa oloogbe naa nitori owo nla kan toun ri lọwọ rẹ.

Lori aṣeyọri nla tawọn ọlọpaa ṣe yii, Kọmiṣanna awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, C.P Afọlabi Babalọla, ti gboṣuba nla fawọn ọmọọṣẹ rẹ gbogbo ti wọn lọọ fọwọ ofin mu ọdaran naa nibi to sa lọ. Bakan naa ni ọga ọlọpaa naa gba awọn araalu nimọran pe gbara ti wọn ba ti fura sawọn eeyan lagbegbe wọn ni ki wọn ti lọọ fi tọ ọlọpaa leti, ko too di ohun nla si wọn lọrun.

Bakan naa lo ni ki awọn ọlọpaa ọhun taari ọdaran to pa ọrẹ rẹ yii si ẹka to n ri sọrọ ẹsun iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ wọn fun iwadii to peye.

Leave a Reply