Nitori ẹsun ipaniyan, aẉon oniṣowo meji dero ẹwọn ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Aje, Mande, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, paṣẹ ki wọn sọ awọn oniṣowo meji kan, Ugochukwu Ukwegwes, ati Ndubishi Ohanusi, sọgba ẹwọn fẹsun pe wọn lọwọ ninu iku ẹgbẹ wọn, Ifeanyi Onwubika, niluu Kosubosu, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara lo wọ afurasi ọdaran mejeeji lọ siwaju ile-ẹjọ, ti wọn si fẹsun ipaniyan kan wọn. Wọn ni mọlẹbi oloogbe Onwubika, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Kosubosu, nijọba Baruten, pe ọkunrin oniṣowo naa lọ si ọja, ti ko si dari wọle mọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa pada ri oku rẹ nigba ti wọn n wa a kiri lẹbaa ọna l’Opopona Kosubosu.
Lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ni wọn ri i pe awọn ẹgbẹ rẹ mejeeji, Ugochukwu Ukwegwes ati Ndubishi Ohanusi, ni wọn lọọ da a lọna, wọn lu u lalubami, ti wọn si fi silẹ ninu agbara ẹjẹ to sokunfa iku rẹ.
Agbefọba, Innocent Owoola, sọ pe wọn ṣi n reti imọran lati ileeṣẹ to n ri si ẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara lori ẹjọ naa, to si ni ki ile-ẹjọ paṣẹ ki awọn afurasi mejeeji wa ni ọgba ẹwọn.
Onidaajọ Abdulganiyu Ajia paṣẹ ki wọn sọ wọn si ọgba ẹwọn, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, osu Kẹjọ, ọdun yii.

Leave a Reply