Nitori ẹsun ipaniyan, ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa eeyan meji l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ẹbun pataki wa fun ẹnikẹni to ba mọ ibi ti awọn ọmọkunrin meji; Rasheed Hamed, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Rasheed Ọkọ-ilu ati Solomon Adefioye Adedimeji, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Solo Iwara, fara pamọ si.

Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ ni Rasheed Ọkọ-ilu, nigba ti Solomon jẹ ọmọ bibi ilu Iwara, nipinlẹ Ọṣun.

Ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita, o ṣalaye pe nitori ẹsun ipaniyan, ifipabanilopọ, idigunjale, biba dukia awọn ẹni ẹlẹni jẹ, ni wọn n wa awọn mejeeji yii si.

Gẹgẹ bi Ọpalọla ṣe ṣalaye, ẹni ọdun marundinlogoji ni Ọkọ-ilu, nigba ti Solo Iwara jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa kilọ pe ẹnikẹni to ba gba eyikeyii lara awọn mejeeji naa sile yoo foju wina ijiya kan naa bii tiwọn, nitori oju ọdaran nijọba yoo fi wo iru ẹni bẹẹ.

O ni ẹbun nla wa fun ẹni to ba kofiri wọn, to si fi to awọn ọlọpaa leti.

Leave a Reply