Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, nile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, sọ akẹkọọ Kwara Poli, Oyediji Temitọpẹ Ridwan, ati akẹgbẹ rẹ, Asimiyu Idris, sẹwọn ọdun meji meji fẹsun pe wọn n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku EFCC, lo wọ Oyediji ati Asimiyu lọ siwaju Onidaajọ Sikiru Oyinloye, fẹsun pe wọn lu jibiti lori ẹrọ ayelujara. Ajọ naa sọ pe Oyediji n pe ara ẹ ni Dave Sayer, ninu oṣu kẹta, ọdun yii, to si n lo wasaapu nọmba yii +1915209228, lati fi lu oyinbo kan, Danny Coffman, ni jibiti owo ti ko din ni eedẹgbẹrin ataabọ ($750) owo ilẹ okeere.
Bakan naa lajọ ọhun tun fẹsun kan Asimiyu pe oun naa n pe ara ẹ ni Nicky Pearl, laarin oṣu kẹfa si ikeje, ọdun yii, lori ibanidọrẹ Facebook, to si lu arakunrin oyinbo kan Martina Stone, ni jibiti irinwo ($400) dọla owo ilẹ Amẹrika.
Andrew Akọja to jẹ asoju ajọ EFCC lo ko gbogbo ẹri siwaju ile-ẹjọ lati fidi otitọ mulẹ. Awọn olujẹjọ naa gba pe loootọ ni wọn jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan wọn.
Onidaajọ Oyinloye dajọ ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri ti olupẹjọ ko siwaju ile-ẹjọ, o han pe loootọ ni awọn olujẹjọ naa jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn, fun idi eyi, ki Oyediji lọọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna igba naira (#200,000), bakan naa ladajọ tun ni ki gbogbo awọn dukia to ko jọ lọna eru di tijọba apapọ ati owo ti wọn ba lọwọ rẹ, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le mẹsan-an naira (#309, 000), ko di tijọba.
Ni ti Asimiyu, Oyinloye ni ki oun naa lọọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000), ki gbogbo dukia to kojọ lọna eru di tijọba apapọ ati owo to din diẹ ni eedẹgbẹta dọla ti wọn ba lọwọ rẹ $470 USD di tijọba.