Faith Adebọla, Eko
Pampẹ ofin ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nni, EFCC, ti mu awọn mọkanla l’Ekoo, jibiti lilu ati gbaju-ẹ atẹ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo’ lẹsun ti wọn fi kan wọn.
Alukoro ileeṣẹ EFCC l’Ekoo, Ọgbẹni Wilson Uwajuren, sọ pe agbegbe Alagbado, nijọba ibilẹ Alimọṣọ, nipinlẹ Eko, lawọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi ọdaran lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lẹyin tawọn ti gbọ finrin finrin pe wọn n ṣe jibiti ‘Yahoo’ ninu ile kan, tawọn si ti n dọdẹ wọn lagbegbe ọhun.
Uwajuren darukọ wọn: Nwomkiro Ekene Jude, Olukọya Oluwadamilare Timilẹhin, Akingbade Mubarak Ayọboye, Adeolu Kọlawọle Oluwafẹmi, Nwankwo Tochuckwu Michael, Kẹhinde Timilẹhin Ajibọla, Adeṣina Deji, Ọlalekan Abiọla, Anthony Ekene Iwuji, Emeka Metuh ati Oluwaṣẹgun Pẹlumi.
Lara irinṣẹ tawọn afurasi ọhun n lo fun iṣẹ buruku wọn tawọn agbofinro ka mọ wọn lọwọ ni foonu oriṣiiriṣii, awọn kọmputa agbeletan, awọn nnkan eelo abanaṣiṣẹ, oogun abẹnu gọngọ, ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin.
Uwajuren ni iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori awọn gende wọnyi, o lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n tọpinpin wọn lahaamọ ajọ EFCC ti wọn ko wọn si.
Laipẹ lo lawọn maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.