Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Adajọ Sikiru Oyinloye tile-ẹjọ giga kan n’Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ Ọmọtọshọ Ọlọrunyọmi Samuel, akẹkọọ Fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintọla, LAUTECH, atawọn meji miiran, Abass Lawal, akẹkọọ Fasiti KWASU, ati Ọlajide Taofeek Adegoke, sẹwọn fẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Ajọ EFCC lo wọ awọn afurasi mẹtẹẹta lọ siwaju Onidaajọ Oyinloye, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, fẹsun pe wọn lu awọn eeyan ni jibiti ifẹ lori ẹrọ ayelujara, awọn olujẹjọ mẹtẹẹta si gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan awọn.
Nigba ti adajọ Oyinloye n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ti oun ti ṣe ayẹwo finnifinni lori awọn ẹri ti ajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ, ti awọn olujẹjọ naa ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, o ni ki Ọmọtọshọ lọọ ṣẹwọn ọdun kan, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, fun ẹsun akọkọ, ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa fun ẹsun keji, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, ki gbogbo dukia to ko jọ lọna eru ati owo ti wọn ba lọwọ rẹ di tijọba apapọ.
Oyinloye ni ki Abbas, lọọ ṣẹwọn ọdun kọọkan lori ẹsun meji ti wọn fi kan an, ti yoo si sẹwọn naa tẹlera tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira lori ẹsun kọọkan, ki gbogbo dukia to ko jọ lọna eru di tijọba apapọ, to fi mọ owo ti wọn ba lọwọ rẹ.
Ni ti Ọlajide, adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun kan lori ẹsun akọkọ, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira, lori ẹsun keji, ko lọọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko sanwo itanran miliọnu mẹta le diẹ naira (N3,107,215), ki gbogbo awọn dukia to ko jọ lọna eru ati owo ti wọn ba lọwọ rẹ di tijọba apapọ.