Ọgbọn miliọnu lawọn agbebọn to ji awọn arinrin-ajo gbe ni Kwara n beere 

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji onimọ ẹrọ Ayọ Alabi ati awọn mẹjọ miiran laarin Oke-Onigbin si Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpodun, nipinlẹ Kwara, ti n beere fun ọgbọn miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

Iroyin ti ALAROYE ri gbọ ni pe awọn ajinigbe ọhun pe ọrẹ ọkan lara awọn ti wọn ji gbe ti orukọ rẹ n jẹ Ọgbẹni Williams Owolabi, ti wọn si sọ pe ọgbọn miliọnu naira lawọn yoo gba lati tu wọn silẹ ni akata wọn.

Onimọ-ẹrọ Ayo Alabi to jẹ ọkan lara awọn arinrin-ajọ mẹsan-an ti awọn ajinigbe ji gbe ni Eleyin, Oke-Onigbin si Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irepodun, nipinlẹ Kwara, ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja, lakooko ti wọn n dari bọ lati Ekiti.

Leave a Reply