Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori ọrọ eto aabo, paapaa bi awọn eeyan ṣe n lo alupupu ta a tun mọ si ọkada fun iwa ọdaran, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ eto iforukọsilẹ fawọn ọlọkada ipinlẹ naa.
Ẹni-ọwọ Idowu Ogedengbe, to jẹ oludamọran fun Gomina Ṣeyi Makinde lo fidi iroyin yii mulẹ nigba ti ẹgbẹ awọn akọroyin ipinlẹ Ọyọ gba a lalejo nile ẹgbẹ wọn n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Nigba ti yoo ba fi to oṣu meloo kan sasiko yii, awọn ọlọkada to ba kuna lati forukọ silẹ lọdọ ìjọba yoo bẹrẹ si i koju ijiya nla.
Ogedengbe ni “Bi awọn ọlọkada ṣe n ya wọ ipinlẹ Ọyọ lẹnu ọjọ mẹta yii, ati bi wọn ṣe n lo ọkada fun iwa ọdaran n kọ ijọba lominu.
“Lẹnu igba ta a bẹrẹ eto yii, awọn ọlọkada ta a ti ṣeto iforukọsilẹ fun ti le lẹgbẹrun marun-un (5,000) niye.
“Ileeṣẹ to n ri si iṣẹ ode ati eto irinna ni ipinlẹ Ọyọ lo n ṣeto yii pẹlu ajọṣepọ ẹka to n moju to akọsilẹ imọ nipa awọn eeyan ipinlẹ yii. Bakan naa la n gbero lati da aṣọ ti gbogbo ọlọkada ipinlẹ yii yoo maa wọ sọrun ati akoto ti wọn yoo maa de sori fun aabo ẹmi wọn lasiko ijanba ori ọkada.
“Awọn akọsilẹ ti a n gba silẹ nipa ọlọkada kọọkan la oo maa lo lati fi wa eyikeyii to ba huwa ọdaran ninu wọn ka, ta a si maa fi iya ti ba tọ si kaluku jẹ ẹ.
Pẹlu eto yii, ti ọlọkada kan ba wọ ipinlẹ Ọyọ lai jẹ pe a ti forukọ rẹ silẹ lọdọ wa, lọgan la maa mu un, nitori eto yii yoo jẹ ṣee ṣe fun wa lati da iru ẹni bẹẹ mọ.”
O waa rọ awọn ọlọkada ti ko ba ti i forukọ silẹ lati ṣe bẹẹ, ko too di pe kinni naa yoo bẹrẹ si i la ijiya lọ fun wọn.