Monisọla Saka
Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti paṣẹ pe ki wọn ti awọn ileewe giga fasiti, atawọn ẹka eto ẹkọ mi-in ti wọn ni ajọṣepọ pẹlu awọn ileewe fasiti kaakiri orilẹ-ede Naijiria pa, bẹrẹ lati ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, titi di ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ikede yii waye latari eto idibo to n bọ lọna ti yoo waye jake-jado orilẹ-ede Naijiria. Lojuna ati le dena rogbodiyan to ṣee ṣe ko waye lagbegbe awọn ileewe, eyi to le ṣe akoba fun ẹmi ati dukia awọn olukọ ati akẹkọọ, ati lati fun awọn akẹkọọ lanfaani lati lọọ dibo fẹni to wu wọn ni wọn ni igbesẹ naa ṣe waye.
Ninu ọrọ ti Adamu Adamu ti i ṣe Minisita feto ẹkọ, gba ẹnu ajọ to n ri si ọrọ fasiti nilẹ yii, NUC sọ ninu ikede (Circular), ti wọn fi ṣọwọ si gbogbo awọn alaṣẹ atawọn adari fasiti, titi mọ awọn ẹka wọn kaakiri ilẹ yii, lo ti rọ gbogbo ile ẹkọ giga pata, lati fi ọgba ileewe silẹ lasiko ibo ta a n wọ lọ yii.
Ninu iwe ipade ti Igbakeji akọwe agba ajọ NUC, Ọgbẹni Chris Maiyaki, buwọ lu lọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn ti ṣalaye pe adari ọrọ ode ninu ajọ naa, Lawal Ajo, fidi ẹ mulẹ pe lati ọdọ awọn ni lẹta ọhun ti jade wa.
Apa kan lẹta naa ka bayii pe, “Gẹgẹ bii ọg agba ileewe giga fasiti, atawọn adari lawọn ile-ẹkọ to ni ajọṣepọ pẹlu fasiti kọọkan, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni ijọba la kalẹ pe eto idibo gbogboogbo ọdun 2023, to jẹ ti aarẹ atawọn aṣofin agba yoo waye, nigba ti ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ Kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, yoo jẹ ọjọ idibo awọn gomina atawọn aṣofin ipinlẹ kọọkan.
“Nitori idi eyi ati nitori aabo fun ẹmi awọn oṣiṣẹ, akẹkọọ atawọn nnkan-ini ijọba lawọn ileewe yii, lẹyin ti Minisita feto ẹkọ nilẹ yii, Malam Adamu Adamu, ti ṣepade pẹlu awọn ileeṣẹ eto aabo tọrọ kan, paṣẹ pe ki gbogbo ileewe giga fasiti atawọn ileewe mi-in to ba ni ajọṣepọ pẹlu wọn, ti ilẹkun ọgba ile-ẹkọ wọn pa, ki wọn si da idanilẹkọọ duro laarin ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun yii, si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2023’’.
Ṣaaju akoko yii ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹ-ede yii, NANS, ti ke pe ijọba apapọ lati ti awọn ileewe wọn pa lasiko ibo yii, kawọn akẹkọọ ti wọn forukọ silẹ lati dibo niluu koowa wọn le ni anfaani lati ṣe bẹẹ