Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua nile loko, ti Ọjọgbọn Banji Akintoye jẹ adari rẹ, ati awọn ọmọ ẹgbẹ naa mẹẹẹdogun miiran ti gba ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti lọ lati da ajọ eleto idibo duro lati ma ṣe ṣe eto idibo si ipo gomina nipinlẹ Ọṣun ati ti Ekiti, eyi ti ajọ naa n mura lati ṣe.
Ninu iwe ipẹjọ naa ti agbẹjọro fun ẹgbẹ ọhun, Ọgbẹni Tolu Babalẹyẹ, pe nile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ekiti lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa bii, Ọjọgbọn Banji Akintoye, Igbakeji adari ẹgbẹ naa, Dokita Wale Adeniran ati akọwe wọn, Dokita Bayo Orire ati awọn mẹẹẹdogun mi-in ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.
Wọn pe fun dida ajọ eleto idibo INEC ati Adajọ agba fun ijọba apapọ, Ọgbẹni Abubakar Malami, duro lati ma ṣeto idibo gomina si ipinlẹ Ọsun ati Ekiti, ayafi ti wọn ba ṣe ayipada si ofin ọdun 1999.
Awọn ẹgbẹ naa ti wọn gba agba agbẹjọro, Tolu Babalẹyẹ, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ondo, tun pe ẹjọ naa nile-ẹjo giga kan ni Oṣogbo, nipinlẹ Ọsun. Wọn ṣalaye pe bi ajọ eleto idibo naa ṣe fẹẹ ṣeto idibo naa ta ko iwe ofin orile-ede Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ buwọ lu, eyi to fun awọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja, ni Ado-Ekiti, sọ pe lai jẹ pe orile-ede Naijiria sọ asọye ati ajọro lati tun iwe ofin ọdun 1999 ṣe, iwe ofin ọdun naa ko ba ofin mu mọ, o ti di aloku.
O ṣalaye pe lilo iwe ofin ọdun 1999 ni idi pataki ti ọmọ ẹgbẹ wọn ṣe gba ile-ẹjọ lọ lati pe ẹjọ ta ko eto idibo naa, ati pe ki ile-ẹjọ da a pe iwe ofin odun 1999 ko ba ofin mu mọ, nitori ko si apero kankan laarin awọn ọmọ orile-ede Naijiria ki wọn too ṣe iwe ofin naa.
Ẹgbẹ naa ni fifagi le iwe ofin ọdun 1999 yii ni yoo fi aaye silẹ fun gbogbo ọmọ ilẹ kaaaro-oo-jiire lati ṣe ifikunlukun lori bi idasilẹ orilẹ-ede Yoruba yoo ṣe di mimuṣẹ.
Wọn waa rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ naa pe ko da ajọ eleto idibo duro lati ma ṣe ṣeto idibo nipinlẹ mejeji naa, ki wọn tun so gbogbo ipinnu wọn ati gbogbo igbesẹ ti wọn ti n gbero lati ṣe lori eto idibo naa rọ ni kiakia.