Nitori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ, TAMPAN fofin de Yọmi Fabiyi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 TAMPAN, ẹgbẹ awọn onitiata, ranṣẹ pe Yọmi Fabiyi lati waa ṣalaye ara ẹ lori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ to gbode kan, nigba to si di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ẹgbẹ fofin de e lai ni igba ti wọn yoo pe e pada, wọn ni iṣẹ to ṣe ninu fiimu naa ko ba ilana awọn mu.

 Atẹjade lawọn TAMPAN fi sita ti wọn fi kede fifofin de Yọmi, ohun ti wọn kọ sibẹ ni pe ọkunrin yii pẹlu Dele Matti to ba a dari iṣẹ naa jẹbi. Wọn ko tẹle ilana to rọ mọ gbigbe ere jade rara.

Wọn ni Dele Matti gba pe oun jẹbi ni tiẹ, nipa  fifi orukọ awọn ti iṣẹlẹ kan ṣere. Eyi to jẹ pe ọrọ Baba Ijẹṣa to wa ni kootu ni wọn sọ di nnkan amuṣere lawujọ.

 Fun pe Dele gba pe oun jẹbi, ẹgbẹ fofin de e foṣu mẹta, ṣugbọn Yọmi Fabiyi ko gba pe oun jẹbi ni tiẹ, niṣe lo ni ẹtọ oun ni gẹgẹ bii olukọtan lati gbe fiimu jade tabi fi iṣẹlẹ awujọ ṣere.

Eyi ko ṣe itẹwọgba fun TAMPAN, wọn ni Yọmi Fabiyi mọ-ọn-mọ ṣe fiimu naa lai tẹle ofin ẹgbẹ ni, bẹẹ, ohun to ṣe yii le da wahala silẹ lawujọ. Wọn ni gbogbo orukọ awọn eeyan to lo ninu fiimu naa n tọka si iṣẹlẹ Baba Ijẹṣa to wa ni kootu, eyi to le mu ede aiyede wa.

TAMPAN sọ pe ohun ti Yọmi ṣe yii ti tabuku ẹgbẹ awọn ju, eyi naa lo si fa a tawọn fi jawee gbele-ẹ le e lọwọ lai nigba kan.

Koda, gbogbo ọmọ ẹgbẹ TAMPAN to kopa ninu sinima ‘Ọkọ Iyabọ’ yii ni ẹgbẹ ti paṣẹ pe ki wọn yọju sigbimọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje yii, ki wọn waa ṣalaye ohun ti wọn ri ki wọn too kopa ninu sinima akoyangan-yangan ba ara abule naa.

Ẹgbẹ yii lawọn ki i ṣe ẹgbẹ adaluru, ọrọ ti yoo ba si da wahala silẹ lawujọ, ẹnikẹni ko ni i ba ọwọ TAMPAN nibẹ rara.

Ṣugbọn Yọmi ko fara mọ idajọ TAMPAN, niṣe loun naa gba ori ayelujara lọ to si kọwe sibẹ pe latilẹ loun ti jẹ ọmọ ẹgbẹ ANTP, patapata ẹ, oun yoo tun ẹgbẹ wọ laarin wọn.

Yọmi loun ko gba fọọmu tabi kọwọ bọwe pẹlu TAMPAN ri. O ni wọn ni koun sanwo iforukọsilẹ, oun san an, ṣugbọn oun ko gba fọọmu lọwọ wọn.

‘’Lẹta ti wọn kọ ko tọna, ko wulo fun emi ti mo jẹ ẹni to n gbe fiimu jade. To ba wu mi lati gbe igbesẹ kan lori iṣẹlẹ yii, lori pe wọn tẹ ẹtọ mi mọlẹ lo maa jẹ. Eeyan ki i padanu ohun ti ko ni tẹlẹ.’’

Bẹẹ ni Yọmi Fabiyi kọwe soju opo Instagraamu rẹ, to si buwọ lu u.

Awọn to n bu u nibẹ lo pọ ju ṣa o, wọn ni ọkunrin naa ko mọ ohun to kan lọrọ rẹ, ati pe agidi to n ba ẹgbẹ lo lasiko yii ko ja mọ nnkan kan.

Ọpọ eeyan lo sọ pe nigba ti TAMPAN n ba Iyabọ Ojo ati Nkechi Blessing wi laipẹ yii, ṣebi Yọmi n kona mọ ọn ni, to n ṣe bii ọmọ ẹgbẹ tootọ. Wọn ni nigba ti tiẹ ba a lasiko yii lo ṣẹṣẹ mọ pe oun ki i ṣe TAMPAN, wọn ni atẹyin kọgbọn aja ni Yọmi Fabiyi, wọn ti ge e leti tan ko too maa fọbẹ pamọ.  

Leave a Reply