Ọlawale Ajao, Ibadan
Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ti yi ẹjọ tawọn agba ijoye ilẹ Ibadan pe danu. Ẹjọ ọhun ni wọn pe tako idajọ to lodi si bi Oloogbe Ajimọbi ti i ṣe gomina ipinlẹ naa tẹlẹ ṣe fi awọn agba ijoye ilu naa jẹ lọdun 2017.
Adajọ agba ipinlẹ Ọyọ, Onidaajọ Munta Abimbọla, lo yii ẹjọ ọhun danu ni yara igbẹjọ kin-in-ni tile-ẹjọ giga ipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji, ọdun 2022 yii.
Itumọ idajọ tuntun yii ni pe bi ijọba Ajimọbi ṣe fawọn agba ijoye wọnyi jọba ko tọna labẹ ofin gẹgẹ bii awijare Osi Olubadan, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja, to pẹjọ naa latilẹ, ti ile-ẹjọ si da a lare nigba naa ko too di pe awọn ijoye to jọba ọhun pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to ṣẹṣẹ pari yii.
Bakan naa nidajọ yii ti mu oludena kuro lọna fun Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Lekan Balogun lati depo Olubadan. Iyẹn ni pe ko si ohun to n di i lọwọ mọ lati jọba bayii.
Tẹ o ba gbagbe, nigba ti Gomina Ajimọbi ṣeto oye ọba fawọn agba ijoye Ibadan lọdun naa, Osi Olubadan, Sẹnetọ Ladọja, to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ kọ lati jọba ọhun, o si pẹjọ tako igbesẹ ijọba naa.
Nigba ti wọn fa ọrọ naa siwaju, fa a sẹyin ni kootu, ile-ẹjọ da Ladọja lare. Ṣugbọn awọn agba ijoye yooku sọ pe bi ijọba ṣe fawọn jọba gan-an lawọn fara mọ, n ni wọn ba gba kootu ko-tẹ-mi-lọrun lọ.
Lẹyin ti Olubadan ana, Ọba Saliu Akanmu Adetunji waja, gbogbo aye lo ti mọ pe Agba-Oye Balogun lo kan lati gori itẹ Olubadan. Ṣugbọn ọrọ ẹjọ ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ yii pe lo n di i lọwọ lati gori ipo naa nitori wọn ko le fi ẹnikẹni ninu awọn to ti jọba tẹlẹ wọnyi jẹ Olubadan laijẹ pe wọn yanju ọrọ to wa ni kootu tan pata.
Ṣugbọn ni bayii tile-ẹjọ ti yi ẹjọ naa danu, ko si ohun to n di Balogun lọwọ mọ bayii lati gori apere ọba ilẹ Ibadan.