Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gomina ipinlẹ ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti fi nọmba ifisun ti i ṣe 112 sita fawọn eeyan ipinlẹ yii lati pe bi wọn ba koju ifiyajẹni lọna aitọ latọdọ awọn agbofinro ilẹ wa.
Gomina fi nọmba naa sita lọjọ Aje ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii, lọfiisi rẹ to wa l’Oke-Mọsan, l’Abẹokuta.
O ṣalaye siwaju pe ifisun yii ko pin lori ọlọpaa nìkan, o ni eyikeyii agbofinro to ba tẹ ẹtọ araalu mọ́lẹ̀ ni wọn le tori rẹ pe nọmba 112 yii, igbakigba ni wọn si le pe e pelu.
Dapọ Abiọdun fi kun un pe bi araalu ba kofiri awọn to n ba dukia ijọba jẹ nitori ẹhonu ti wọn n ṣe, ki wọn pe 112 lati ṣalaye ibi ti iwa ibajẹ naa ti n waye, ki wọn fi eyi to ku silẹ funjọba.
Gomina ko ṣai ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn lasiko rogbodiyan SARS to kọja kẹdun, bẹẹ lo gboriyin fawọn ọdọ ipinlẹ Ogun fun bi wọn ṣe tete gbọ ìkìlọ̀ ijọba lasiko iwọde naa, ti wọn ko jẹ ko di wahala ti apa ijọba ko ka, bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọọta kan lọwọ si i lasiko kan.
Bakan naa lo kilọ fawọn to ba ṣi n lero láti fa wahala kan tabi omi-in lati ma dan an wo, nitori iya ti yoo jẹ wọn lori ẹ wa nilẹ sẹpẹsẹpẹ ni.