Ọlawale Ajao, Ibadan
Ohun eelo ọbẹ̀ bíi ata, tòmáàtì, àlùbọ́sà, titi dori ẹran námọ̀ ati ẹ̀wà ti di ọ̀wọ́n gógó n’Ibadan ati kaakiri ipinlẹ Ọyọ bayii nitori bi awọn Hausa ti wọn n pese awọn nnkan wọnyi ṣe pinnu pé àwọn kò ní í ko ounjẹ wọlu Ibadan mọ.
Ìpinnu awọn Hausa yii kò ṣẹ̀yìn ija to waye laarin Yoruba atawọn Hausa lẹyin ti Hausa alábàárù kan lu Yoruba kan to jẹ soobata pa ninu ọja Ṣáṣá, n’Ibadan, lọsẹ mẹta sẹyin.
Tẹ o ba gbagbe, ninu ifọrọwerọ ti Sarikin Hausa, ìyẹn ọba awọn Hausa ni Ṣáṣá, Alhaji Haruna Mai Yasin, ṣe pẹlu akoroyin wa, eyi to jade ninu ALAROYE ọsẹ to kọja, lọkunrin naa ti ti sọ pe awọn Hausa ko ni í jẹ kí ìrè oko wọn ti wọn ba n gbe bọ wá fun títà lati ilẹ Hausa wọ Ibadan mọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ipinlẹ Eko láwọn yóò máa gbé àwọn oúnjẹ naa lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu ifọrọwerọ ọhun, “Ohun ti awọn Yoruba ṣe fun wa, a o mọ pe o le ṣẹlẹ. Gbogbo wa ti sọ pe a fẹẹ maa ko pada lọ siluu wa. Awọn ijọba wa lókè gan-an ti sanwo ọkọ awọn kan pe ki wọn maa bọ wa silẹ Hausa. Eeyan ọgọrun-un (100) ni wọn ti sanwo baaluu wọn pe ki wọn fi maa pada bọ wale.
“Wọn ni ọjọ meji lẹyin naa lawọn maa sọ fun awọn Yoruba to wa nilẹ Hausa naa pe ki wọn kuro lọdọ awọn naa. Bakan naa, gbogbo ounjẹ to n wọle lati ilẹ Hausa, irẹsi ni o, ẹwa, ata ni o, alubọsa ni o, adiẹ ni o, Eko ni wọn yoo maa gbe e lọ, wọn ko ni i jẹ ko de Ibadan mọ nitori gbogbo iṣoro ti wọn fẹẹ maa fun wa yii. Ṣugbọn a ti pada ba awọn eeyan wa sọrọ pe ki wọn jẹ ka yanju ẹ.”
Awọn Hausa ti waa mu ileri ọhún ṣẹ bayii, lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keji, ọdún 2021 yii. Wọn ko ko awọn nnkan ìsebẹ̀ wọ Ibadan mọ, ti awọn nnkan ọhun sì ti wọ́n bíi oju kaakiri ipinlẹ Ọyọ bayii.
Awọn alata to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe ko fẹẹ sí ọjà ti eeyan ti le ri ata rà láràtúntà níbikíbi niluu Ibadan ati agbegbe ẹ̀ mọ bayii nitori pe awọn Hausa to n ko àwọn ọja naa wa lọpọ yanturu fún títà ti da igbesẹ naa duro.
Gẹgẹ bí òbínrin alata kan to pera ẹ ni Iya Hikima ṣe ṣalaye fakọroyin wa, “O fẹẹ jẹ pe ọja Ṣáṣá ni gbogbo awa ti a n ṣòwò ata ti máa n rajà. Ṣugbọn lati igba ti ìjọba ti ṣi Ṣáṣá pada lọsẹ to kọja, Bódìjà ati ọja ilu Ìròkò la ti n lọọ ra eelo bayii.
Ati Bódìjà o, ati Ìròkò ni o, kò sí ibi kankan tá a ti n ri ata rà mọ bayii lati ijarun-un (Tọ́sìdeè).
“Èkó lo tún kù ti awọn eeyan wa kan ti n lọọ ra eelo wa. Ìdí ree ti ata fi gbowo leri nitori ìwọ̀nba ninu wa lo lagbara lati maa ti Ibadan lọọ ra ra eelo l’Ekoo. Ohun to si jẹ ki wọn maa ta a wọn niyẹn nítorí kì í ṣe owo kekere ni wọ́n fi n ko ọja yẹn lati Eko.”
Titi ta a fi parí akojọ iroyin yii lọsan-an ọjọ Ajé, Mọnde, ọsẹ yii, ata atawọn ohun eelo ọbẹ yooku ti di ọwọngogo.
Ọwọngogo epo bẹtiroolu to wa lóde bayii lo túbọ̀ dá kún ipọnju ara ipinlẹ Ọyọ pẹlu bi ọpọlọpọ ileepo ṣe tilẹkun ileetaja wọn pa, ti epo bẹtiroolu si di ohun ti awọn eeyan n daamu wá kiri.
Eyi papaa ti jẹ kí owo ti awọn araalu fi n wọ mọto pọ̀ sí i, ti gbogbo nnkan si gbowo lori sí i.