Stephen Ajagbe, Ilorin
Latari ijamba ọkọ to ṣẹlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, eyi to sọ akẹkọọ Poli Ọffa meji dero ilewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju, to si tun da omi alaafia agbegbe naa ru, awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti kede isinmi ọjọ meji.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, Ọgbẹni Ọlayinka Iroye, gbe sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, lo ti ni ileewe ọhun gbe igbesẹ naa lati ma faaye gba ohun to le tubọ da ruke-rudo silẹ.
O ni isinmi naa bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii, titi di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii. Ọjọ Aje, Mọnde, lawọn akẹkọọ yoo pada sẹnu ẹkọ wọn.
Ọlayinka rọ awọn akẹkọọ lati gba alaafia laaye pẹlu bo ṣe ni ara awọn to farapa ninu ijamba naa ti n balẹ nilewosan ti wọn ti n gba itọju.
Ijamba ọhun lo ṣẹlẹ lọna Ọffa si Ojoku, lasiko ti awakọ Toyota Camry kan kọ lu kẹkẹ Maruwa tawọn akẹkọọ naa wọ.
Eeyan mẹrin la gbọ pe wọn padanu ẹmi wọn.