Nitori ike omi, Bernard sọ baba ẹ loko pa

Jọkẹ Amori

Ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn mu ọmokunrin kan torukọ re n jẹ Bernard Denlami, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbon, ni yoo ti ṣalaye ohun to fa a to fi wo sunsun, to si sọ baba rẹ loko pa.

Ipinlẹ Plateau, nijọba ibilẹ Mangu, ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ. Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa,  Onyeka Bartholomew, lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ilu Jọs.

O ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹeje alẹ ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla yii, ni awọn gba ipe pe ija nla kan bẹ silẹ laarin tẹgbọn-taburo kan,

Barnard Danlami, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati aburo rẹ, Zugumnan Danlami, ẹni ọdun mọkandinlogun, lori bọkẹẹti omi.

Baba awọn ọmọ mejeeji yii da si ija naa, o si da eyi ẹgbọn lẹbi pe iwa afojudi lo hu si oun lori ọrọ naa, lo ba lu u lẹgba. Sugbọn idajọ baba yii ko bọ si ara rere lọdọ Barnard, niṣe lo si mu okuta nla kan nilẹ, to sọ ọ lu baba rẹ niwaju ori.

Ọgbẹ ti baba naa ni latari okuta to sọ mọ ọn yii lo ṣeku pa a, nitori ẹjẹ to pọ ju to da lara rẹ.

Oju-ẹsẹ ti wọn fi ọrọ yii to awọn ọlọpaa leti ni wọn ti lọọ mu ọmọ to pa baba rẹ naa.

Kọmiṣanna  ọlọpaa ni ni kete tawọn ba ti pari iwadii lori ọrọ yii ni wọn yoo gbe afurasi naa lọ sile-ẹjọ.

 

Leave a Reply