Nitori ikọlu Fulani, awọn gomina ilẹ Yoruba fẹẹ pawọ-pọ lori eto aabo

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ninu atẹjade ti Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ti sọrọ naa faye gbọ.

Akeredolu to tun jẹ alaga igbimọ awọn gomina ilẹ Yoruba lẹkun Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii, ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹ bii igbesẹ ojo pẹlu bo ṣe jẹ pe ilu to n gbe lalaafia jẹẹjẹ wọn ni awọn Fulani naa lọọ ṣakọlu si.

Gege bo ṣe sọ, “Nigba ta a ṣi n reti abajade iwadii ti awọn agbofinro maa ṣe lori iṣẹlẹ yii, a n fi asiko yii sọ fawọn oludari ikọ Amọtẹkun kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii lati ṣepade lori bi wọn yoo ṣe maa ṣiṣẹ ajumọṣe lati papọ lati dena ti iru iṣẹlẹ yii lọjo iwaju.”

Ṣaaju ikọlu yii lalaga ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Kunle Togun, ti kegbajare sita nipa bi awọn Fulani ti wọn wa lati ilẹ okeere ṣe ya wọ agbegbe Oke-Ogun, ti wọn si ti fara pamọ sinu igbo nibẹ lati maa ṣe awọn eeyan ni suta lọjọ iwaju.

Igbagbọ awọn ara ilu Igangan kan to ba akọroyin wa sọrọ ni pe awọn agbaagba ilu lagbegbe Ibarapa lapapọ lo ro awọn Fulani lagbara bẹẹ lati maa fiya jẹ awọn araalu bẹẹ.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Sunday Akinbọade to jẹ olugbe agbegbe yii ṣe sọ, “Awa funra wa la fọwọ ara wa fa sọọlọ. Awọn adari atawọn aṣaaju wa ti faaye gba awọn Fulani ju bo ṣe yẹ lọ.  niṣe lawọn ọba atawọn baale kan maa n fun awọn Fulani wọnyi nilẹ lọfẹẹ nitori maaluu ti awọn yẹn n fun wọn.

Wọn n pe ibi kan ni Alagolo, lagbegbe Ibarapa yẹn, boya la ri Yoruba kan ṣoṣo to n gbebẹ, kikidaa Fulani nikan lo wa nibẹ. Bẹẹ lọja to wa ni AUD naa, o fẹẹ jẹ kiki awọn Fulani lo n naja yẹn naa. Wọn ti ti ọja yẹn pa bayii, wahala awọn Fulani naa ni ko jẹ ki wọn na an mọ.”

Laaarọ ọjọ Satide ọhun lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, atawọn lọgaalọgaa lẹnu iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣabẹwo siluu Igangan, to si ṣeleri lati ṣewadii to lagbara nipa iṣẹlẹ naa, ti oun yoo si mu awọn to huwa ọdaran naa fún iya jẹ nilana ofin.

Leave a Reply