Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
O ti di eewọ nipinlẹ Ogun bayii lati maa ti ọmọlanke ti wọn fi n kọ idọti kiri. Ijọba ti paṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ ba awọn to n ti kẹkẹ naa dowo-pọ mọ, awọn akolẹ ijọba ni wọn ni ki wọn maa gbe idọti wọn fun bayii.
Yatọ si eyi, eewọ ni fun ẹnikẹni lati maa ya ojule awọn eeyan pẹlu ọmọlanke yii pe ki wọn gbe idọti wọn wa. Ijọba yoo mu ẹnikẹni tọwọ ba tẹ to tun ti n kẹkẹ ikolẹ kiri bayii ni, wọn yoo si ba kẹkẹ ọhun jẹ loju-ẹsẹ.
Oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lori eto ayika, to tun jẹ ọga agba pata fawọn ajọ akolẹ-ko-idọti nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ọla Ọrẹsanya, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣegun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 2020, niluu Abẹokuta.
Ọrẹsanya ṣalaye pe ọpọ igba lawọn to n ti ọmọlanke kiri yii ko waa ko idọti, ole ni wọn waa ja nile ẹni to n fi aimọkan gbe idọti fun wọn.
O ni nigba tawọn onibaara wọn ba fẹẹ gbe idọti fawọn eeyan naa, ti ọpọlọpọ wọn ki i tiẹ ṣe ọmọ orilẹ-ede yii rara, wọn yoo ṣilẹkun ọgba wọn kalẹ pe ki wọn wọle waa gbe idọti, asiko naa lawọn to n fi ilẹ kiko boju yii yoo ka iye ọkọ to wa ninu ọgba, ti wọn yoo foju wo bi ẹni to ni ile naa ṣe to, ohun to si kan ni ki wọn fi to awọn adigunjale ẹgbẹ wọn leti, n ni wọn yoo ba ṣigun waa ba onile, ni wọn yoo ba ja a lole gidi.
Yatọ si ti ole jija, ọga ajọ akole-ko-idọti ipinlẹ Ogun naa ṣalaye pe awọn to n fi ọmọlanke ko idọti kiri yii n dọti ilu, nitori ibi to ba wu wọn ni wọn n pada da a si, wọn ki i tẹle aṣẹ ijọba.
Fun idi eyi, o rọ awọn eeyan ipinlẹ yii lati ba ijọba dowo-pọ nipa gbigbe ilẹ wọn sibi to yẹ, ti awọn oṣiṣẹ to lẹtọọ lati gbe e yoo si ṣe bẹẹ lọna to ba ofin mu. Idọti ti n di owo nisinyii gẹgẹ bo ṣe wi, nitori awọn nnkan kan ṣe e sọ di tuntun ninu awọn idọti tawọn eeyan n danu, eyi si jẹ ọna ipese iṣẹ ati ounjẹ oojọ fawọn kan ni.