Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Adeboye, ni arun Korona ko ni i lọ, afi…

 

Jide Alabi

Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Enoch Adeboye, ti sọ pe ni gbogbo igba ti wọn ba ti n ṣawari oogun to le kapa arun Koronafairọọsi yii ni aisan buruku mi-in yoo tun maa foju han si i.

Baba Adeboye sọ pe bi iṣelẹ yoo ṣe maa ṣẹlẹ ree titi ti awọn alagbara aye yoo fi gba pe Ọlọrun nikan lo ni iṣọ to peye lọdọ.

Lasiko to n sọ nipa iran ti Ọlọrun fi han an fun ọdun 2021 ni baba naa sọrọ yii nibi isin aṣewọnu ọdun tuntun, eyi to waye lori ikanni ayelujara.

O ni lara ohun to ṣẹlẹ lọdun 2020 yii lawọn eeyan yoo tun ba pade ninu ọdun 2021. Bẹẹ lo fi kun un pe ohun to le ko agbaye yọ lọwọ oriṣiriiṣi iṣẹlẹ aburu niwọnyi ni pe: awọn eeyan gbọdọ gba pe Ọlọrun nikan lọba to n dari akoso ẹda, ki i ṣe imọ sayẹnsi gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe Daniẹli, ori kẹrin, ẹsẹ kẹẹẹdọgbọn.

Bakan naa lo sọ pe ọmọ eeyan gbọdọ gba pe Ọlọrun nikan lo n fun ni lọgbọn, bẹẹ lo le sọ ẹni to ro pe oun gbọn yẹn di omugọ patapata.

Ṣiwaju si i, o ni gbogbo ete ati ọgbọn ti awọn eeyan ba n lo lati fi wa oogun ti yoo kapa arun Koronafairọọsi lawọn aisan buruku mi-in to fara jọ ọ yoo tun maa ṣẹ yọ, afigba ti awọn alagbara aye ba gba pe Ọlọrun nikan lo ni iṣọ lọdọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe Owe, ori kọkanlelogun, ẹsẹ kọkanlelọgbọn.

Alagba Adeboye ni Ọlọrun ti ni funra oun loun yoo maa da sẹria fawọn orilẹ-ede to n tapa si aṣẹ oun, afi ti wọn ba tọrọ aforiji ẹṣẹ pelu adura gidigidi.

Tẹ o ba gbagbe, bi ọdun 2020 ṣe n kasẹ nilẹ lawọn ileeṣẹ apoogun kan sọ pe awọn ti ri ọna abayọ si oogun to le kapa arun Koronafairọọsi. Bakan naa ni ajọ to n ri si eto ilera lagbaaye naa sọ pe laipẹ ni apa yoo kan arun ọhun pẹlu bi wọn ṣe wa ojuutu si oogun to le kapa ẹ bayii.

Ṣugbọn pẹlu ọna abayọ ti wọn sọ pe wọn ti ri yii, bẹẹ lawọn arun mi-in to fara pẹ Koronafairọọsi ti n ṣẹ yọ lawọn orilẹ-ede kan bayii, ti kinni ọhun si ti fẹẹ maa burẹkẹ mọ wọn lọwọ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: