Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Nitori iwọde SARS to n lọ lọwọ kaakiri awọn ipinle nilẹ wa, eyi ti ko yọ ipinle Ondo sile, Gomina Rotimi Akeredolu ti ni ki wọn ti gbogbo awọn ileewe to wa nipinlẹ naa pa lẹyẹ-o-ṣọka.
Ikede yii waye lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ eto ẹkọ ati imọ sayẹnsi ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn akẹkọọ ọhun ṣẹṣẹ n wọle pada lẹyin bii osu meje sẹyin tí wọn ti wa nile latari arun korona.
Ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, lawọn obi kan ti wọn n sa kijokijo lati lọọ mu awọn ọmọ wọn to ti lọ sileewe lẹyin ti wọn ṣakiyesi pe iwọde to n lọ naa lọwọ ti fẹju kọja bo ṣe yẹ.