Nitori iwọde SARS, ijọba ipinlẹ Ondo kede konilegbele

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Gomina Rotimi Akeredolu ti kede ofin konilegbele ni gbogbo ipinlẹ Ondo latari iwọde SARS to n lọ lọwọ.

Ikede yii waye ninu ọrọ ti gomina ọhun bawọn eeyan sọ lagọọ meje alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii, ofin yii lo ni yoo bẹrẹ laago mejila oru ọjọ naa titi dọjọ mi-in ọjọ ire.

Yatọ si awọn ti iṣẹ wọn ṣe koko laarin ilu, o ni ko ni i si aaye fun ẹnikẹni lati maa rin kiri, bẹẹ ni ko gbọdọ si tita tabi rira nibikibi laarin asiko ti ofin naa ba fi wa nita.

 

 

Leave a Reply