Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọrọ yii tabi omi-in lọpọ ero kootu ibilẹ kan nigboro Ibadan n tẹnumọ nigba ti lanlọọdu kan, Ọlalekan Ọlasunkanmi, ẹni to fẹẹ le tẹnanti rẹ kuro nile sọ pe ọbun ṣiọṣiọ layalegbe oun naa, odidi ọjọ bii mẹta lo fi maa n rẹ aṣọ sinu omi ko too fọ ọ lẹyin to ba ti lo wọn dọti nilokulo tan.
Njẹ bawo lo ṣe mọ aṣiri ayalegbe ẹ to bẹẹ, Ọlasunkanmi sọ pe ko ṣoro foun lati mọ nipa obinrin naa daadaa nitori ibi oju windo oun lo ti maa n fọ pata atawọn awọtẹlẹ rẹ gbogbo.
Ṣaaju ni baba onile yii ti rọ ile-ẹjọ lati le ayalegbe naa jade ninu ile oun nitori yatọ si pe o jẹ oun lẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (15,000) ti i ṣe owo oṣu mẹfa fun yara kan to rẹnti ninu ile oun, niṣe lobinrin naa maa n kọ orin owe mọ oun ninu ile, ti yoo si maa fi oun wọlẹ niṣeju awọn ayalegbe yooku.
O waarọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun Fọlakẹ lati san gbese to jẹ oun, ko si ko jade ninu ile oun kiakia.
Ṣugbọn tẹnanti yii sọ pe kile-ẹjọ ma da baba lanlọọdu yẹn lohun, ko jẹwọ ohun to n ṣe e ni, o lo pẹ to ti fẹẹ maa ba oun sun, ṣugbọn ti oun ko gba, iyẹn lo ṣe fẹẹ kanra le oun jade nile ẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Gbogbo igba ti wọn ba ti ri ọkunrin pẹlu mi lara maa n kan wọn. Lọjọ kan ni wọn bẹrẹ si i bu mi loju afẹsọna mi. ohun to si n ka wọn lara ni pe iṣeju wọn la fi wọle lalẹ ọjọ yẹn, gbogbo ba a ṣe n bara wa laṣepọ ni wọn n gburoo ninu yara wọn, wọn mọ pe a gbadun ara wa gan-an lọjọ yẹn, iyẹn ni wọn ṣe n kanra mọ emi ati afẹsọna mi nigba ti ilẹ ọjọ keji mọ.”
Kia ni baba to pẹjọ naa han ọrọ mọ olujẹjọ lẹnu, o ni “ẹ ma da a lohun o, Oluwa mi, aṣẹwo paraku lobinrin tẹ ẹ n wo yii, ko si ọmọluabi kọbọ kan lara ẹ. Nigba to kọkọ waa ba mi pe oun fẹẹ gbale, eeyan gidi ni mo pe e nigba naa lọhun-un, ko ju oṣu mẹta lọ to wọle tan lo bẹrẹ si i fa awọn iwa kebekebe ọwọ ẹ yọ si mi lọkọọkan.
“Ohun to sọ fun mi nigba naa ni pe oun ko lọkọ. Ṣugbọn ọkan-o-jọkan ọkunrin lo maa n gbe waa sunle lalaalẹ. Nigba mi-in, yoo yọ jade ninu ile lalẹ patapata, lasiko ti gbogbo wa ba ti sun, bo ba si ti n lọ ni yoo tilẹkun sita, ti yoo si ti emi atawọn tẹnanti ẹgbẹ ẹ yooku mọle.
“Ọkan ninu awọn tẹnanti mi to tirafu lọjọ yẹn, ṣugbọn to pẹẹ wọle lo jẹ ki aṣiri tu nigba to ri i pe ita ni wọn tilẹkun si dipo ki wọn ti i sinu gẹgẹ ba a ṣe maa n ti i nigba ta a ba fẹẹ sun lalẹ.
“Gbogbo awọn tẹnanti lo jade sita lọjọ yẹn lati mọ ẹni to ti gbogbo wa mọnu ile, afi oun (Fọlakẹ) nikan. Iyẹn gan-an lo tu u laṣiiri pe oun lo tilẹkun làtìsíta lalẹ ọjọ yẹn.
“Lati mọ amọdaju ẹni to ṣi kinni yẹn, mo paarọ kọkọrọ ẹnu geeti. Bi Fọlakẹ ṣe de ni idaji ọjọ keji lo bẹrẹ si i jan okuta mọ kọkọrọ, o fẹẹ jalẹkun ko le raaye wọle. Kaka ko kabaamọ fun iwa aidaa to hu, eebu lo n bu mi, to tun bẹrẹ si i gbe mi ṣepe. Bo ṣe maa n ṣe niyẹn, ojo epe ati eebu lo maa n rọ le mi lori ṣaa ni gbogbo igba.”
Ninu idajọ ẹ, adajọ kootu naa ti paṣẹ fun Fọlakẹ lati san gbese to jẹ baba onile ẹ, ko si ko jade ninu ile naa, o pẹ ju, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun 2020, ta a wa yii.