Nitori obinrin, Danladi gun ọrẹ rẹ pa l’Ode-Aye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Money Danladi, ni wọn ti fẹsun kan pe o gun ọrẹ rẹ, Sunday Babaji, lọbẹ pa lasiko tawọn mejeeji n jọ n ja lori ọrọ obinrin.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, abule kan ti wọn n pe ni Badokun, nitosi Ode-Aye, nijọba ibilẹ Okitipupa, ni Danladi ati Sunday n gbe.
Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lọkunrin to n ṣiṣẹ lebira ọhun pe Sunday to jẹ ọrẹ ati alabaaṣiṣẹpọ rẹ, to si fẹsun kan an pe o n fẹ ọrẹbinrin oun, ẹni ta a forukọ bo laṣiiri.
Danladi ni fifẹ ti ọkunrin ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa n fẹ ọrẹbinrin oun ko dun oun bii ẹnu to tun n fọn kiri fawọn eeyan pe oun ti ba obinrin naa sun lọpọ igba.
Ọrọ yii lo da wahala silẹ laarin awọn ọrẹ meji ọhun lọjọ naa, leyii to ṣokunfa bi Danladi ṣe binu fa ọbẹ yọ, eyi to fi gun ọrẹ rẹ pa.
Kiakia lawọn ara abule naa lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa tesan Ode-Aye leti, ti wọn si waa fi pampẹ ofin gbe afurasi apaayan ọhun lai fi akoko falẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn agbofinro wọ Danladi lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, pẹlu ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Agbefọba, Nelson Akintimẹhin, ni ko si aniani pe afurasi ọhun ti ṣẹ si abala okoolelọọọdunrun din ẹyọ kan (319) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Akintimẹhin ni oun fẹ ki kootu ọhun paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Gbogbo ibeere agbefọba ni Onidaajọ Musa Al-Yunus buwọ lu nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ.
Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ladajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: