Nitori oju ọna to bajẹ kọja sisọ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹhonu han, wọn di marosẹ Eko si Abẹokuta pa

Faith Adebọla, Eko

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, ẹka tipinlẹ Eko ati Ogun, ti ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ lori titi marosẹ Eko si Abẹokuta, latari iwọde ati ifẹhonu han ti wọn gun le l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, wọn ni ipo ti ọna naa wa ti buru kọja afarada, inira ati adanu to si n fa faraalu ti pọ ju.

Agbegbe Sango lawọn oṣiṣẹ naa ti pade, ibẹ ni wọn kora jọ si, pẹlu oriṣiiriṣii akọle ti wọn gbe dani, ti wọn si n kọrin ọkan-o-jọkan lati fi aidunnu wọn han si bijọba ko ṣe kọbiara si atunṣe ọna ọhun titi dasiko yii.

Lara akọle naa ka pe: “A o fẹ palietiifu, niṣe ni kẹ ẹ ṣe ọna gidi fun wa,” “Dapọ Abiọdun, gba wa lọwọ ọna jakujaku yii,” “A o ki i ṣe ẹru lorileede wa, ẹ ma sọ wa d’ẹru,” ati “Ọna yii ti di koto iku, ma pa wa danu o,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Alaga ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Emmanuel Bankọle, to ba Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), sọrọ, sọ pe: “A o ni i gba ki ẹnikẹni tẹ ẹtọ wa mọlẹ. Niru asiko yii, a o ni ọna mi-in ju ka jẹ kijọba mọ binu wa ko ṣe dun to lọ.”

Kọmureedi naa sọ pe gbedeke ọjọ mọkanlelogun tawọn fun Minisita ọrọ iṣe ode ati ile gbigbe nilẹ wa, Babatunde Raji Faṣọla, ti pari, sibẹ ko si igbesẹ atunṣe kan lori ọna ti ko daa ọhun. O ni ileri ti Fasọla ṣe ni pe awọn maa bẹrẹ atunṣe ranpẹ si ọna naa, ṣugbọn ati atunṣe ranpẹ ati atunṣe gidi, awọn o ri ohunkohun.

Bakan naa ni alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ tipinlẹ Eko, Abilekọ Funmi Ṣessi, sọ pe “ọrọ ti kọja ileri ori ahọn, igbesẹ gidi la n reti latọdọ ijọba, akoko ti lọ fun ọrọ sisọ, ijọba gbọdọ mu aye dẹrun faraalu, inira yii ti pọ ju.”

O ṣalaye pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ mejeeji pawọ-pọ lati ṣewọde ọhun nitori gbogbo arọwa ati ẹbẹ tawọn ti n ṣe lori ipo ti ọna naa wa ko tu irun kan lara ijọba, niṣe ni wọn kọti ọgbọin si i titi tọna naa fi bajẹ kọja aala.

Obinrin naa ni lẹyin iwọde yii, ti ijọba ko ba gbe igbesẹ to yẹ lori atunṣe kiakia, awọn yoo ṣepade lati pinnu awọn igbesẹ to lagbara mi-in tawọn maa gbe laipẹ.

CAPTION

Leave a Reply