Faith Adebọla
Titi dasiko yii ni awuyewuye ṣi n lọ lori iku Dokita kan, Arabinrin Vwaere Diaso, ẹni to padanu ẹmi rẹ sinu ẹrọ agbeni-roke gbeni-resalẹ, ti wọn n pe ni lift tabi elevator, amọ iṣẹlẹ tuntun to wọ ọrọ naa ni pe Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti paṣẹ pe ki ọga agba ajọ to n ri si amojuto awọn ẹrọ ati irinṣẹ gbogbo to jẹ tijọba nipinlẹ Eko, Lagos State Infrastructure and Asset Management Agency (LASIAMA), Abilekọ Adenikẹ Adekanbi, dawọ iṣẹ duro lẹyẹ-o-sọka, wọn ni kobinrin naa lọọ rọọkun nile, latari iṣẹlẹ ọhun.
Sẹria naa ko duro lori Adenikẹ nikan, gomina tun paṣẹ pe oun ko fẹẹ ri eyikeyii ninu awọn manija ti wọn n ṣabojuto awọn ẹrọ abanaṣiṣẹ ijọba naa mọ rara, o ni ki gbogbo wọn pọ soke raja, o gbaṣẹ lọwọ wọn! Wọn o gbaṣẹ lọwọ wọn bẹẹ lasan o, Sanwo-Olu tun ni ki wọn kọ orukọ gbogbo wọn sinu iwe akọọlẹ ati iwe iranti nipinlẹ Eko, pe eyikeyii ninu wọn ko gbọdọ ni ohunkohun iṣe nibi iṣẹ ijọba mọ, o ni ki wọn to wọn sara awọn ọbayejẹ tijọba ko gbọdọ ba da nnkan pọ mọ titi aye.
Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti Akọwe agba lẹka iroyin ati ọgbọn-inu nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olumide Ṣogunlẹ, fi lede fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfai oṣu Kẹjọ yii.
Wọn ni igbesẹ yii waye latari abajade iwadii ijinlẹ ti igbimọ ọlọfintoto kan ti Gomina Sanwo-Olu gbe kalẹ lọsẹ to kọja pe ki wọn lọọ tana wodi ohun to ṣokunfa ijamba ẹrọ naa debi to fi gbẹmi Dokita Vwaere lọjọ Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ yii, lasiko to wa ninu ẹ lọsibitu ijọba to wa lagbegbe Ọdan, l’Erekuṣu Eko lọhun-un.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ yii, ni igbimọ ọhun jabọ iwadii wọn fun Sanwo-Olu, ti gomina si ṣeleri pe gbogbo awọn ti wọn ba jẹbi lọna kan tabi omi-in, tabi ti iwa idagunla, fifọwọ hẹ iṣẹ, ati abuku mi-in ba wa lara ohun to ṣokunfa iku ojiji yii ni yoo ri pipọn oju ijọba Eko.
ALAROYE gbọ pe gbogbo aba ti igbimọ oluṣewadii naa kọ silẹ ninu abọ iwadii wọn ni Sanwo-Olu faṣẹ si pe ko di mimuṣẹ lẹsẹkẹsẹ.
Gomina tun sọ pe oun ti fọwọ si i, oun si ti paṣẹ fawọn agbofinro lati tubọ ṣewadii ẹnikẹni mi-in to ba han pa aikunju oṣunwọn rẹ lo fa ijamba yii, o ni ki wọn palẹ onitọhun mọ, ki wọn si jẹ kiru ẹni bẹẹ kawọ pọnyin rojọ ni kootu.
Ẹ oo ranti pe ọrọ iku ojiji to pa dokita yii ti da awuyewuye silẹ pẹlu bileegbimọ aṣofin Eko ṣe sọ lọsẹ to kọja pe awọn naa maa tọpa bọho iṣẹlẹ ọhun, tawọn yoo si ṣepinnu to tọ lori ẹni yoowu to ba jẹbi iku Dokita Diaso.
Ẹgbẹ awọn dokita ti lawọn maa gun le iyanṣẹlodi lawọn osibitu tọrọ naa kan lati fi aidunnu wọn han si iku aitọjọ to mu ẹmi ẹlẹgbẹ wọn yii lọ.