Nitori ọrọ aabo, Sheikh Gumi ṣabẹwo s’Ọbasanjọ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Gbajugbaja Aafaa ilu Kaduna nni, Sheikh Ahmad Gumi, ti ṣabẹwo si aarẹ Naijiria tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, niluu Abẹokuta, nitori ọrọ aabo orilẹ-ede yii to mẹhẹ.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ni Gumi ko ikọ lẹyin, ti wọn ba Ọbasanjọ ṣepade atilẹkun mọri ṣe nile baba naa to wa ni OOPL, l’Abẹokuta.

Koko abẹwo naa bo ṣe lu sawọn akọroyin lọwọ ni pe Sheikh Gumi ṣalaye fun Ọbasanjọ nipa irinajo to rin lọ sọdọ awọn Fulani agbebọn ti wọn n jiiyan gbe lapa Ariwa Naijiria.

O ni igbagbọ oun ni pe ijọba apapọ yoo ri aba toun gbe kalẹ lati fa awọn eeyan naa mọra bii imọran to daa, ati ọna kan ti wọn le fi ṣẹgun iṣoro ijinigbe ati jagidijagan, ti yoo si seso rere gan-an ti wọn ba le gba a wọle.

Ọbasanjọ ati Gumi tilẹ jọ kọwọ bọwe kan ti wọn lawọn fi gba pe iṣoro ijinigbe, idigunjale atawọn iwa ọdaran mi-in ti kari Naijiria. Wọn lawọn gba pe awọn eeyan lati orilẹ-ede yii, ati lawọn ilẹ ibomi-in ni wọn n lọwọ si awọn iṣoro yii, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹya kan pọ ninu ẹ ju awọn mi-in lọ.

Wọn tun lawọn gba pe ibi ti eto aabo mẹhẹ de ni Naijiria bayii ti kọja afarada, eyi lo si fa a ti Gumi fi ti Kaduna waa ba Ọbasanjọ l’Abẹokuta lati jiroro lori ẹ.

Aikawe to awọn kan, ọrọ-aje to rugọgọ jura wọn lọ lawọn ibomi-in, iyapa ẹsin ati ẹya, wa ninu awọn ohun to n fa iṣoro aabo nilẹ yii bi wọn ṣe wi, bẹẹ lawọn oloṣelu onijibiti naa n da kun un pẹlu.

Lati ṣẹgun iṣoro gbogbo to n koju Naijiria yii, Gumi ati Ọbasanjọ sọ pe ọna meji ni. Wọn ni awọn ajinigbe atawọn agbebọn ti wọn gba lati ṣiwọ iwakiwa yii, kijọba fa wọn mọra. Ki wọn ko wọn kuro ninu igbo, ki wọn wa ile ti wọn yoo maa gbe fun wọn pẹlu iṣẹ ti wọn yoo maa ṣe.

Awọn to ya pooki ti wọn ko fẹẹ yipada ninu iwa ọdaran, wọn ni kijọba da sẹria to yẹ fun wọn bọwọ ba tẹ wọn, ki wọn fimu wọn danrin.

Bẹẹ ni wọn ni ijọba apapọ gbọdọ ji giri si ojuṣẹ ẹ nipa aabo, nitori bi nnkan ṣe wa yii ko ṣẹ rara ni.

Ko gbọdọ si ninaka aleebu sẹnikẹni bi a ba fẹẹ tete ri ere igbesẹ ti wọn ni kijọba gbe yii, kaka bẹẹ, wọn ni ki gbogbo ọmọ Naijiria ri aabo bii ohun ti gbogbo wa yoo jọ jija ẹ, titi ti yoo fi ri bo ṣe yẹ ko ri ni.

Bakan naa ni wọn sọ pe iṣoro yii ko le dopin, nigba ti awọn ipinlẹ kan ba n ba awọn ajinigbe dunaa-dura nipa iye owo ti wọn yoo fi gba eeyan wọn ti wọn ji gbe silẹ, to si jẹ pe awọn kan n ba wọn ja, wọn n yinbọn fun wọn ni.

Wọn ni gbogbo agbegbe ni wọn gbọdọ ro lagbara lati koju awọn to n kọ lu wọn lojiji, bẹẹ si ni ẹbun to jọju gbọdọ maa wa fawọn to ba ta ijọba lolobo nipa awọn agbebọn wọnyi, ko le maa jẹ koriya fun wọn lati ṣe ju bẹẹ lọ.

Fawọn tọwọ ba tẹ pe wọn n lọwọ si ijinigbe atawọn wahala yooku, wọn ni kijọba da ile-ẹjọ pataki kan silẹ ti ko ni i gbọ ẹjọ mi-in ju tiwọn lọ, ti wọn yoo si ti maa da sẹria to ba yẹ fun wọn labẹ ofin. Ẹnikẹni ti wọn ba si ri to n gbe nnkan ija kiri lai gbaṣẹ ijọba, wọn ni kijọba da sẹria gidi fun un.

Lakootan, Sheikh Gumi sọ fun Oloye Ọbasanjọ pe koun naa wa si Kaduna, kawọn tun jọ wo ọrọ aabo yii wo, kawọn si le fori awọn ọna abayọ yii ti sibi kan.

Ọbasanjọ naa loun gba lati lọ si Kaduna, ṣebi ki nnkan le daa naa ni.

Ọba Agura, Babajide Bakre, wa nibi ipade naa. Biṣọọbu Tunde Akinsanya, alaga CAN nipinlẹ Ogun naa wa nibẹ pẹlu Sheikh Sa’addallah Alade Bamigbola, Imaamu agba ilẹ Ẹgba, Oloye Kenny Martins, Oloye Babajide Jaiyeọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply