Nitori ọrọ Baba Ijẹṣa to fi ṣe fiimu, awọn oṣere binu si Yọmi Fabiyi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Inu buruku lo n bi awọn oṣere tiata Yoruba kan si akẹgbẹ wọn,Yọmi Fabiyi,bayii. Eyi ko ṣẹyin sinima rẹ, ‘Ọkọ Iyabọ’ to ti n po pọ latigba ti ọrọ Baba Ijẹṣa ti bẹrẹ, ṣugbọn to ti jade bayii. Iṣẹ ọhun lawọn eeyan ẹ wo ti wọn si bẹrẹ si i sọrọ odi si i.

Mercy Aigbe wa lara awọn to koro oju si fiimu Yọmi, ori ẹka Instagraamu ẹ lo ti fi aiduunu rẹ han si fiimu naa, ohun ti Mercy sọ sibẹ ree

“ Bawo ni waa ṣe maa fi ohun inira ẹni keji rẹ ṣere bii eyi, ika eeyan nikan lo le dan iru eyi wo. Ibi kan ṣoṣo ti mo wo ninu iṣẹ rẹ yii fi han pe o ko ro ti ara yooku mọ tiẹ rara. Ko tiẹ ba ohun to yẹ mu rara ni, o si kooyan niriira”  

Alesh Ọla Sanni ko tiẹ gba pe ọkunrin ni Yọmi, Aunti Yọmi lo pe e nigba to bẹrẹ ọrọ tiẹ pe, “ A ti gba pe Aunti Yọmi Fabiyi ti ya were, wọn si nilo itọju, kin waa ni ka pe tawọn to ba a kopa ninu fiimu naa atawọn ti wọn jọ ṣiṣẹ ninu ẹ.

“To ba digba mi-in, ẹ maa ka ohun ti itan tẹ ẹ fẹẹ ṣe ba n sọ daadaa kẹ ẹ jẹ ko yeyin kẹ ẹ too bọ siwaju kamẹra. Gbogbo oriburuku yii ko le pe yin rara.”

Ẹlomi-in to tun sọrọ lori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ ni oṣere ti wọn n pe ni Temitọpe Ṣolaja. Oṣere naa kọ ọ pe, ‘Emi ko ki n sọrọ ti ko ba yẹ, ṣugbọn awọn ọrọ kan wa ti ko yẹ keeyan dakẹ lori rẹ. Iru ẹ ni eyi ti mo fẹẹ sọ yii.Yọmi Fabiyi ṣe afihan bo ṣe jẹ alailojuti si. Ko si idi kan to fi yẹ ki ẹnikẹni sọ ohun to n dun ẹlomi-in lọkan tabi ohun ti ẹni yẹn n la kọja di nnkan yẹyẹ. Ohun ti o fi han pẹlu eyi ti o ṣe yii ni pe o ko lẹkọọ, o ko ni aanu ẹlomi-in, o si jẹ apẹẹrẹ ọkan ninu awọn ohun to n ṣe Naijiria lonii ti wọn ba n sọrọ nipa ṣiṣe ọmọde baṣubaṣu. Itiju nla ni fiimu naa, ki i ṣe iṣẹ ọpọlọ rara. To o ba ni itiju, to o si ni ọwọ fun ara rẹ, niṣe ni wa a sọ fiimu naa kalẹ lẹyẹ o ṣọka.’

‘Fun ẹni to n pe ara rẹ ni baba, oju gba mi ti fun ọ.’’

Ọpọ eeyan lo n bu Yọmi lẹka awọn to n da si ọrọ naa, wọn ni ki i ṣe pe o nifẹẹ Baba Ijẹṣa to pe lọrẹẹ ẹ lo fi gbe fiimu yii kalẹ, ọpọ wọn lo n sọ pe ero inu Yọmi Fabiyi ko daa si ọmọlakeji ẹ rara ni.

Ẹni ti ko ba ti i wo fiimu ọhun ko le mọ ohun to fa a tawọn eeyan rẹ fi n binu buruku si i bayii, ṣugbọn ko sẹni kan to gba awọn eeyan nimọran lati lọọ wo o, ohun ti Yọmi Fabiyi fi ṣere naa n mu inu rẹ bi wọn gidi ni.

Leave a Reply