Ọlawale Ajao, Ibadan
Laaarọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ opin ọsẹ yii ni awọn oloye ẹgbẹ Igbimọ Agba ilẹ Ibadan bii marun-un ṣepade nile Oloye Rasidi Adewọlu Ladọja to wa ni Bodija, niluu Ibadan.
Awọn ọmọ igbimọ naa, ninu eyi ti Alaga wọn, Oloye Yẹmisi Adeaga, Oloye Dọtun Sanusi ati ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ, Baalẹ Yẹmi Ogunyẹmi pẹlu awọn meji mi-in wa ni wọn wọle ipade pẹlu gomina Ọyọ tẹlẹ naa.
Fun bii odidi wakati kan le diẹ lawọn eeyan naa fi tilẹkun mọri, ti wọn ko si gba oniroyin kankan laaye lati wọnu ile pẹlu wọn.
Ipade naa ko sẹyin bi gbogbo nnkan yoo ṣe lọ bo ṣe yẹ ko lọ lori ẹni ti yoo jẹ Olubadan ilẹ Ibadan gẹgẹ bi ẹnikan ṣe fi to ALAROYE leti.
Lẹyin ti wọn pari ipade ọhun lawọn oniroyin sun mọ wọn lati mọ ohun ti wọn tori ẹ pepade, ṣugbọn awọn eeyan naa ko ba oniroyin kankan sọrọ. Alaga wọn, Oloye Adeaga, kan sọ pe ko si wahala kankan, o ni gbogbo ọrọ ti yanju, ki awọn eeyan fọkan balẹ.
Bakan naa ni ẹnikan yọ sọ fun ALAROYE pe Oloye Lekan Balogun ti gbogbo eeyan gbagbọ pe ipo naa tọ si paapaa ti pe Oloye Adewọlu Ladọja sori aago l‘Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ṣugbọn ko sẹni to mọ ohun ti wọn jọ bara wọn sọ.
Ohun tawọn to mọ bo ṣe n lọ sọ fun ALAROYE ni pe gbogbo ọna ni awọn eeyan n wa bayii lati ri i pe oju ko ti Oloye Lekan Balogun, ati pe o bọ sori apere gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan.
Ṣugbọn ti eleyii yoo ba wa si imuṣẹ, pupọ ọrọ naa wa lọwọ Oloye Adewọlu Ladọja gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, nitori ọkunrin naa ni ipa pataki lati ko lori ẹjọ to wa nile-ẹjọ ati Gomina Ṣeyi Makinde ti ọrọ wa lọwọ rẹ lati buwọ lu ẹni ti wọn yan gẹgẹ bii Olubadan.
Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe Ladọja ati Makinde sun mọ ara wọn, gomina naa yoo si fẹẹ ṣe ohun ti Ladọja ba fẹ.
Bẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, ọsidee, oṣẹ yii ni Ladọja sọrọ lori redio kan, nibi to ti sọ pe ki awọn eeyan yee pariwo oun lori ọrọ oye ilẹ Ibadan. O ni ki ọn rọ Lekan Balogun ko lọọ fa iwe ẹjọ to pe si kootu ya to ba mọ pe oun fẹẹ jẹ Olubadan.
Wẹsidee, Ọjọruu, ti i ṣe ọjọ karun-un, oṣu yii ni awọn Oloye ilẹ Ibadan pe jọ si, nibi ti wọn ti kede Oloye Lekan Balogun gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun. Ṣugbọn ko ti i le bọ sori apere naa, afi ti gomina ba fọwọ si i.
Idiwọ to le wa nibẹ ni bi Gomina Ṣeyi Makinde ba tẹle imọran Amofin agba, Micheal Fọlọrunṣọ Lana, to gba a pe ko ma ti i fọwọ si Olubadan ti ipo naa kan nitori ẹjọ to wa nile-ẹjọ lori ade ti gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Oloogbe Isiaka Ajimọbi, fun awọn igbimọ Olubadan, eyi to si ti da awuyewuye silẹ, ti ọrọ naa si ti de ile-ẹjọ.
Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo fori sọ.