Adewale Adeoye
Pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n jade lati fi aidunnu wọn han lori iku aitọjọ to pa ọdọmọkunrin olorin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad, ọkan ninu awọn gbajumọ oṣere ilẹ wa, Iyabọ Ojo, ti sọ pe gbogbo ohun to ba gba pata loun maa fun un lati ri i pe awọn to wa nidii bi gbajumọ olorin taka-sufee nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad ṣe ku lai tọjọ maa jiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe.
Lara igbesẹ ti Iyabo Ojo loun maa gbe ni pe oun maa gbe ọrọ naa lọ siwaju ajọ aladaani kan toun jẹ adari rẹ lati mojuto bọrọ naa ṣe maa niyanju laipẹ ọjọ. Yatọ si eyi, o loun ti sọ fun lọọya oun kan pe ko ṣe gbogbo ohun to ba yẹ pata lori ọrọ naa ko le pe Naira Marley, Sam Larry ati gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa pata lẹjọ.
Iyabo Ojo ni, ‘Mo mọ daadaa pe iku to pa oloogbe Mohbad ki i ṣe lati ọdọ Ọlọrun rara, awọn oṣika kan ni wọn wa nidii iṣẹlẹ naa. Ẹni akọkọ ti ma a si tọka si pe o lọwọ ninu iku irawo olorin ọhun ni ọga rẹ tẹlẹ, Naira Marley. Ọwọ rẹ ko mọ rara. Gbara tọmọ ọhun ti fi ileeṣẹ rẹ ‘Marlian Records’ silẹ lo ti n lepa ẹmi ọmọ naa, to si n fiku waa kaakiri. Oun nikan kọ o, amugbalẹgbẹẹ rẹ naa ti i ṣe Sam Larry paapaa wa lara awọn to pa oloogbe naa. Ọpọ fidio oniṣẹju diẹ lo ti gba igboro kan bayii nibi ti aworan Sam Larry ti han to ti n lu oloogbe naa gidi. Wọn halẹ mọ ọn titi to fi ku ni. Awọn eeyan ti mo darukọ yii gan-an ni wọn ran oniṣẹ iku si i, ẹri wa daadaa. Mo ti sọ fun ajọ kan ti mo n dari rẹ pe ki wọn gbaradi lati ba awọn to pa Mohbad ṣẹjọ, a maa ṣe ba a ti ṣe ṣe ẹni to fipa b’ọmọde sun yẹn ni, o si daju pe a maa ri idajọ ododo gba.
‘‘Lọọya mi paapaa ti wa ni ikalẹ bayii, oun naa ti ṣetan lati gbe ọrọ ọhun lọ si kootu. Eyi ki i ṣe eyi tawọn ẹbi oloogbe naa a waa sọ pe awọn ko lowo lọwọ lati ṣẹjọ o.
‘‘Ilu-mọ-ọn ka ni oloogbe yii, o di dandan ka ran an lọwọ lati ri idajọ ododo gba bọ lati ọdọ ijọba ni. Mo n fi akoko yii ke sawọn gbajumọ bii: Davido, Wizkid ati bẹẹ bẹẹ lọ pe ki wọn dide sọrọ ọhun, Mohbad gbọdọ ri idajọ ododo gba ni. Ni bayii, mo ṣetan lati ṣaaju iwọde ita gbangba nitori ọrọ ọmọ ti wọn pa laipe ọjọ yii. Bakan naa ni mo si n rọ ẹyin abiyamọ pe ki ẹ ma sun lori ọrọ yii rara.
Ọba Elegushi paapaa gbọdọ jọwọ Sam Larry silẹ bayii ni, mo mọ pe eeyan yin ni, ṣugbọn ohun to ṣe ki i ṣe nnkan to daa rara. Gomina ipinlẹ Eko gbọdọ ran wa lọwọ ni, awọn ọlọpaa gbọdọ ṣe oootọ lori ọrọ naa, awọn abiyamọ gbogbo gbọdọ dide iranlọwọ sọrọ yii. Iku Mohbad ko gbọdọ lọ bẹẹ yẹn rara. Oju awọn aṣebi gbọdọ han kedere ni.