Nitori ọrọ owo iranwọ epo bẹntiroolu, Falana ṣabẹwo si Tinubu

Monisọla Saka

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni agba agbẹjọro nilẹ wa to tun jẹ lọọya ajafẹtọọ ọmọniyan, Fẹmi Falana (SAN), ṣabẹwo si Aarẹ Bọla Tinubu, nile ijọba, niluu Abuja, fun ipade pataki lori ọna abayọ si iyanṣẹlodi tawọn oṣiṣẹ fẹẹ gun le, eyi to waye latari owo iranwọ epo ti ijọba kede pe awọn ti yọ.

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ ni Falana ti i ṣe agbẹjọro ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ Naijiria, Nigerian Labour Congress (NLC), lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti sọ pe ọna lati gbogun ti iwa jẹgudujẹra wa lara ohun ti ipade naa da le lori, ṣugbọn ohun tawọn tori ẹ jokoo ipade gan-an jẹ wiwa ọna abayọ si iyanṣẹlodi tawọn oṣiṣẹ fẹẹ bẹrẹ, eyi to le tubọ mu ki eto ọrọ aje Naijiria dẹnu kọlẹ si i.

O ni bo tilẹ jẹ pe erongba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ni lati sọ iwa ajẹbanu di ọrọ itan lorilẹ-ede yii, ọrọ naa doju ru, o si di ẹti fun ijọba rẹ, lẹyin tawọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ bẹrẹ si i ṣe owo ilu baṣubaṣu, lai si ẹnikẹni to le yẹ wọn lọwọ wo.

O ni, “Loootọ ni mo ṣepade pẹlu Aarẹ Tinubu. Ọrọ owo iranwọ epo, ọna lati dena fifi ọrọ̀ ilu ṣofo ati ba a ṣe fẹẹ ri owo ti wọn ji ko pamọ gba pada ni a sọ. Lọrọ kan, koko ipade wa ni ọna lati mu agbedide ba ọrọ aje wa to ti n ku lọ”.

Ṣaaju akoko yii ni Tinubu ti sọ pe awọn olowo nilẹ Naijiria ni wọn n ko ere owo iranwọ ori epo tijọba n san da si apo ara wọn lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, tawọn mẹkunnu si n yíràá ninu ìṣẹ́ ati oṣi. Owo iranwọ yii lo ni dipo ki oun maa san an lọ, ko si maa bọ sọwọ awọn eeyan kan, awọn yoo lo o lati fi ṣe awọn nnkan amayedẹrun sinu ilu.

Latari bi epo ṣe gbowo lori, tawọn ọlọja naa si ti fowo le nnkan ti wọn n ta yii, ti ko si si ẹkunwo owo-oṣu fawọn oṣiṣẹ lo mu kawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ jake-jado orilẹ-ede yii fi ikilọ ọlọjọ meje fa ijọba Tinubu leti, wọn ni ti ko ba wa nnkan ṣe si i titi di Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, awọn yoo daṣẹ silẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

 

Leave a Reply