Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ọjọ marun-un ti ọmọ Yahoo kan binu fi mọto kọ lu eeyan rẹpẹtẹ niluu Akinmọọrin, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ ọdun tuntun, ọkunrin awakọ kan tun ti mọ-ọn-mọ fi mọto pa ọlọkada kan laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, niṣẹlẹ naa waye, nigba ti awakọ ọhun, Adeoye Adekunle, mọ-ọn-mọ fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti nọnba rẹ jẹ EKY 337 EL gun ẹni naa lori, ti onitọhun si tibẹ dero ọrun.
Ẹni ti afurasi ọdaran naa fi mọto pa, Godwin Agbo, to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ iṣowo ori ẹrọ ayelujara kan ti wọn n pe ni Jumia, lo maa n fi ọkada gbe ọja lọọ fun awọn onibaara to ba raja lọwọ ileeṣẹ naa.
Ẹnu iṣẹ lọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) to n gun ọkada fun ileeṣẹ Jumia yii wa ti ede-aiyede fi bẹ silẹ laarin oun pẹlu Adekunle onimọto ayọkẹlẹ nigba ti wọn jọ n du ọna rin nitosi ileepo Forte Oil, laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe ọna ni Agbo ati Adekunle n du mọra wọn lọwọ ti ọrọ naa fi dija nla laarin wọn, ọkunrin ọmọ Ibo naa lo gun ọkada nigunkugun to fi bi ọkunrin onimọto naa ninu.
Lẹyin ti awọn onija mejeeji yii ti pariwo lera wọn lori daadaa ni Agbo ṣina fun okada rẹ, to n sare lọ, ṣugbọn Adekunle naa fibinu sare buruku tẹle e pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti wọn n pe ni Lexus SUV, titi to fi mọ-ọn-mọ kọ lu u, to tun gun un lori mọlẹ ko too bẹrẹ si sa lọ lẹyin to fi mọto rẹ gbẹmi ẹniẹlẹni tan.
Bo tilẹ jẹ pe akọroyin wa ko ti i ri Adekunle ba sọrọ, ohun ti wọn lafurasi ọdaran naa n tẹnu mọ gẹgẹ bii awijare ẹ ni pe loootọ lede-aiyede waye laarin oun pẹlu Agbo, ṣugbọn ọkunrin ọlọkada naa lo kọkọ lẹko mọ oun laiṣẹ lairo, to si bẹrẹ si i sa lọ pẹlu ọkada rẹ ki oun naa too maa fi mọto oun le e lọ.
Ileewosan mejeeji ti wọn sare gbe Agbo lọ ni wọn ti kọ lati gba a silẹ fun itọju nitori to ti ku ki wọn too gbe e dọdọ wọn.
Ọkan ninu awọn oniṣowo adugbo naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ ṣalaye pe “ere buruku lonimọto yẹn sa lasiko iṣẹlẹ yẹn. Nṣe lo kọ lu ọkunrin ọlọkada yẹn, to si gun un lori mọlẹ. Lẹyin naa lonimọto yẹn gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn awọn eeyan pada ri i mu niwaju.
“Ki i ṣe loju-ẹsẹ ti mọto gun ọlọkada yẹn mọlẹ lo ku. Ni gbogbo igba ti awọn eeyan n le onimọto yẹn lọ, emi ni mo bẹ awọn eeyan pe ki wọn jẹ ka kọkọ du ẹmi ọlọkada yẹn na. Ṣugbọn nigba ta a fi maa de Ileewosan aladaani ta a gbe e lọ, o ti dakẹ, iyẹn ni ko jẹ ka ri ẹni to maa gba lati tọju ẹ ninu ọsibitu mejeeji ta a gbe e lọ.
Aburo oloogbe, Agbo Emmanuel, ẹni to fiṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa kan nigboro Ibadan fi aidunnu ẹ han si ọwọ ti wọn fi mu iwadii iṣẹlẹ ọhun ni teṣan naa.
O lo da bii ẹni pe ibaṣepọ kan ti wa laarin afurasi apaayan ọhun pẹlu DPO, iyẹn ọga ọlọpaa teṣan yii tẹlẹ, n lo ba kegbajare tọ SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lọ.
Ṣugbọn Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe ko si aaye fun ẹnikẹni lati daṣọ bo iwa ọdaran, niṣe ni ki aburo oloogbe kọwe ẹsun nipa ẹdun ọkan rẹ si CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ. Lọgan to si ṣe bẹẹ lolori awọn agbofinro ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki wọn ṣewadii ọrọ naa bo ṣe tọ, ki wọn si gbe igbesẹ to ba yẹ lori ẹ lẹyin naa.
“Gẹgẹ bii aṣẹ ti ọga ọlọpaa ipinlẹ yii (CP Williams) pa, wọn ti gbe iwadii iṣẹlẹ yii lọ si ẹka ileeṣẹ wa to n tọpinpin iṣẹlẹ ipaniyan ni Iyaganku, n’Ibadan. Wọn si maa gbe ẹjọ yẹn lọ si kootu ni kete ti iwadii alagbara ti wọn n ṣe naa ba ti pari. Bẹẹ ni SP Ọṣifẹṣọ fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa n’Ibadan.