Nitori owo epo mọto, awọn ọmọ Naijiria binu si Buhari

Oko ọrọ ati ọrọ ibinu loriṣiriṣii lawọn ọmọ Naijiria n fi ranṣẹ si olori orilẹ-ede yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ati ijọba rẹ, nitori bi wọn ṣe tun fi kun owo epo mọto lojiji. Lanaa ode yii ni iroyin jade lati ọdọ awọn elepo bẹntiroolu pe Naira mọkanlelaadọjọ (151) lawọn yoo maa ta lita epo kan, yatọ si ogoje ti wọn n ta a tẹlẹ. Ṣugbọn awọn alagbata ti wọn n gbe epo naa kiri sọ pe kò pé awọn lati ta a ni iye naa, awọn yoo owo fi gbigbe ati irinna kun un, afaimọ si ni owo lita epo kan ko ni i sun mọ ọgọjọ Naira (N160).

Ohun to n bi awọn ọmọ Naijiria ninu ree, nitori ọrọ naa ba wọn lojiji, wọn ko si ronu pe ijọba Buhari yoo tun ṣe bayii rara. Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilẹ wa paapaa ti sọrọ, wọn ni ijọba yii n foju tẹmbẹlu awọn ọmọ Naijiria, wọn n foju di wọn, wọn n ro pe wọn ko le ṣe nnkan kan, bẹẹ ti wọn ba sun kan ogiri, wọn yoo ṣe mẹwaa fun wọn. Awọn apapọ ẹgbe oṣẹlu naa sọrọ, wọn ni lasiko ti gbogbo orilẹ-ede agbaye n wa ọna lati din iṣoro ati inira ti ọrọ ajakalẹ-arun Korona ko ba wọn ku, niṣe ni ijọba tiwa n wa ọna lati tubọ maa ni awọn eeyan tiwọn lara.

Ohun to n dun awọn mi-in ju ni pe wọn ranti asiko ti awọn Buhari n ṣe ipolongo ibo lọdun 2015, ariwo ti wọn n pa ni pe owo ti wọn n ta epo bẹntiroolu nigba naa ti pọ ju, lara ohun ti awọn yoo si kọkọ ṣe ni gbara ti awọn ba wọle ni lati ri i pe awọn din owo epo naa ku. Ṣugbọn lati igba ti wọn ti wọle, oke ni ẹmu i ru si ni, nitori  Naira mẹtadinlaadọrun-un (N87) ni wọn n ta epo yii laye Jonathan, lati ọjọ ti Buhari si ti gbajọba, kinni ọhun ko wa silẹ ri, ojoojmọ lo n lọ soke si i.

2 thoughts on “Nitori owo epo mọto, awọn ọmọ Naijiria binu si Buhari

Leave a Reply